Awọn aṣofin n jiroro lati yọ igbakeji gomina Ọyọ nipo

Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbogbo eto ti to bayii lati paarọ ọfiisi Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan.

Eyi ko ṣẹyin bi baba naa ṣe fi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), silẹ, to si gba inu ẹgbẹ All Progressives Congress lọ.
Gẹgẹ bi iwadii ALAROYE ṣe fidi ẹ mulẹ, ọfiisi kan nileeṣẹ eto iṣẹ ode, ti awọn oloyinbo n pe ni Ministry of Works ni wọn n ṣeto lati gbe Ẹnjinnia Ọlaniyan lọ.
Ba a ṣe n kọ iroyin yii lọwọ, awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ tun ti n ṣepade lọwọ lati yọ ọkunrin naa nipo patapata.
Lonii yii (ọjọ Iṣẹgun, Tusidee) naa lẹgbẹ oṣelu PDP Kede orukọ ẹlomi-in ti wọn fi rọpo Ọlaniyan gẹgẹ bii ẹni ti yoo dupo igbakeji Gomina Makinde ninu idibo gbogbogboo ọdun 2023.
Alaga nigba kan ri fun ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ilegbee fun ijọba ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Bayọ Lawal, ẹni ta a ti sọ tẹlẹ pe Gomina Makinde funra rẹ fẹẹ yan, lẹgbẹ oṣelu Alaburada papa kede lati dupo igbakeji gomina, nigba ti GSM ba n wa a ko pẹlu awọn oludije latinu ẹgbẹ oṣelu mi-in gbogbo lasiko idibo ọdun to n bọ.

Leave a Reply