Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹwọn ọdun mẹta lai ni owo itanran ninu, gbigbẹsẹ le ẹranko to jẹ’ko oloko atawọn ijiya mi-in ni ileegbimọ aṣofin Ogun ti dabaa rẹ bayii lati fi gbogun ti fifẹran jẹko to n da wahala silẹ laarin Fulani atawọn agbẹ nipinlẹ Ogun.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹjọ, oṣu keje, ọdun 2021, ni wọn dabaa naa nilbi ijokoo wọn ni Oke-Mosan, l’Abẹokuta.
Ọnarebu Ganiu Oyedeji to n ṣoju Ifọ keji lo gbe aba yii kalẹ, oun naa lo si ka abajade ipade rẹ pẹlu ẹka ọgbin ati igbo ọba fawọn aṣofin yooku.
Awọn aṣofin naa sọ pe idasilẹ ibujẹ ẹran fawọn to n sin maaluu lo daa ju, ki wọn wa ibi ti wọn yoo ti maa sin wọn lai jẹ pe wọn n ko wọn jẹ kaakiri, eyi to n bi wahala ati itajẹsilẹ kaakiri orilẹ-ede yii.
Wọn ni darandaran tọwọ ba tẹ nibi to ti n fẹran jẹko kiri, awọn fẹ ki ofin mu un, ko ṣẹwọn ọdun mẹta o kere ju, lai saaye owo itanran.
Yatọ si eyi, wọn lawọn fẹ kijọba gbẹsẹ le ẹranko yoowu to ba daran naa, ko le maa jẹ arikọgbọn fawọn mi-in ti wọn ba tun fẹẹ ṣe bẹẹ.
Ọnarebu Yusuf Sherif to n ṣoju Ado-Odo-Ọta kin-in-ni lo fọwọ si kika aba yii fun igba kẹta ninu ile naa. Ọnarebu Wahab Haruna to n ṣoju Yewa keji si kin in lẹyin. Nigba naa ni Akọwe ileegbimọ, Deji Adeyẹmọ, ka a setiigbọ gbogbo aṣofin lẹẹkan si i.
Olori wọn, Ọnarebu Taiwo Oluọmọ, paṣẹ pe ki wọn fi ẹda aba ti wọn da yii ṣọwọ si Gomina Dapọ Abiọdun lati buwọ lu.
Bi gomina ba buwọ lu u, o dofin niyẹn.