Awọn aṣofin Ogun kilọ fun Goriọla Hassan, wọn ni ko yee pera ẹ lọba Imobi-Ijẹbu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti ranṣẹ ikilọ si Ọgbẹni Goriọla Hassan, ọkunrin onitiata to n pe ara ẹ lọba ilu Imobi-Ijẹbu, nipinlẹ Ogun, lati yee pe ara ẹ lọba mọ.

Bẹẹ ni wọn ni ko waa foju kan ile naa lori ọrọ yii lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, oun atawọn baalẹ mẹrindinlogoji Imobi ti ọrọ yii kan, wọn lọlọpaa lawọn yoo fi gbe e bi ko ba wa.

Lasan kọ ni awọn aṣofin bẹrẹ ikilọ fun Goriọla, ọkọ Ayọ Adesanya onitiata tẹlẹ, nitori ọrọ wa lori bi ọkunrin naa ṣe n pe ara ẹ lọba lai ti i jẹ pe ijọba atawọn tọrọ kan fun un laṣẹ gẹgẹ bii ọba ni.  Bakan naa ni ẹgbẹ Imobi Descendant Union kọwẹ ifisun sileegbimọ yii, wọn ni Goriọla ki i ṣe ọba awọn, o si n pe ara ẹ lọba.

Yatọ si eyi, awọn aṣofin yii sọ pe eyi kọ ni igba akọkọ tawọn yoo ranṣẹ pe Goriọla Hassan lati waa yanju ọrọ ọlọbade naa, ṣugbọn ti ko wa. Wọn ni to ba tun kọ ti ko wa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, tawọn pe e yii, awọn yoo kọwe ti ọlọpaa yoo fi mu un lọwọ kan ni.

A gbọ pe loootọ ni ọkunrin yii lẹtọọ lati de ori aleefa ọba Imobi, ṣugbọn eto ko ti i waye fun un lati di ọba. Bẹẹ ni ijọba ipinlẹ Ogun lẹka oye jijẹ ko ti i faṣẹ si i ko di ọba ko too maa ṣe iṣe ọba, to si tun n ba awọn akọroyin sọrọ gẹgẹ bii alaṣẹ Imobi-Ijẹbu, iyẹn ni ẹkun Ila-Oorun Ijẹbu.

Yatọ si Goriọla Hassan, ile tun paṣẹ pe ki Ọgbẹni Ademọla Eletu Asorota, to n pe ara ẹ ni Ọba Itele-Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo, yee pe ara ẹ bẹẹ mọ, wọn ni ko sẹnikan to fi i jọba.

Igbimọ to n ri si ọrọ oye jije nileegbimọ, eyi ti Ọnarebu Bọlanle Ajayi dari, lo kilọ naa lasiko ti wọn n ṣepade lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, pẹlu awọn aṣoju ẹbi Adogun Atele, ati lọọya to n ṣoju fun Ọlọta ti Ọta, Ọba Abdulkabir Ọbalanlẹgẹ.

Igbimọ yii paṣẹ pe ki gbogbo igun to n ṣeto ọba jijẹ fun Ademọla Eletu Asorota da gbogbo eto duro na, titi ti ile-ẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ọrọ ọba naa, nitori ẹjọ rẹ wa ni kootu lọwọlọwọ.

Wọn rọ awọn araalu Itele lati ma ṣe foya, wọn ni ki wọn maa gba alaafia laaye lọ bo ṣe wa niluu, ki wọn si dena rogbodiyan yoowu to ba fẹẹ waye lori ọrọ ọba.

 

Leave a Reply