‘Awọn abinu-ẹni oloṣelu lo pa Bọla Ige’

Niluu Ibadan, ni ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, ni ọmọ Oloogbe Bọla Ige, Muyiwa Ige, sọrọ kan lasiko ti wọn n ṣe ayajọ ọjọọbi baba rẹ ti iba pe ẹni aadọrun-un ọdun (90) ka ni pe o ṣi wa loke eepẹ pe nitori owu gbigbona to n da awọn eeyan kan to n da ti awọn ti baba oun jọ wa ninu oṣelu laamu ni wọn fi pa a danu.

Ninu St Anne’s Church, Mọlete, n’Ibadan, nibi ti isin iranti naa ti waye lo ti sọrọ ọhun. Muyiwa fi kun ọrọ ẹ wi pe bi baba oun ṣe fẹran awọn ọdọ, to si ni agbọye fun wọn lo maa n bi awọn ẹgbẹ ẹ kan nidii oṣelu ninu, eyi to dibajẹ si wọn lara, ti wọn fi ṣeku pa a laipe ọjọ

Ọmọ oloogbe yii ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe wọn ṣeku pa ọkunrin oloṣelu yii, sibẹ, oun nigbagbọ pe baba naa wa saye, bẹẹ lo ṣe iwọn to le ṣe, to si jẹ ohun manigbagbe titi lae.

Tẹ o ba gbagbe, titi di asiko yii ni wọn ko ti i ri ẹni to pa gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, to tun pada jẹ olori eto idajọ lorilẹ-ede yii ninu ijọba Ọbasanjọ ọhun.

Leave a Reply