Awọn adajọ bii mẹjọ ni yoo ṣoju Sunday Igboho nile-ẹjọ ni Benin

Faith Adebọla

Awọn adajọ bii mẹjọ lo ti n gbara di lati yọju si ile-ẹjọ giga to wa ni Rue 447, Cotonou, Benin 02BP2004, ilu Cotonou, lorileede Benin, ti igbẹjọ Sunday Igboho yoo ti waye ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii.

Nigba to n sọrọ nipa bi igbẹjọ naa yoo ṣe lọ fun ileeṣẹ tẹlifiṣan Heritage, Ọmọwe Falọla to jẹ olori awọn agbẹjọro ti yoo duro fun Sunday Igboho nile-ẹjọ sọ pe awọn agbẹjọro bii mẹjọ lo ti wa nikalẹ lati lọ si kootu laaarọ ọjọ Aje. O ni agbẹjọro ọmọ Yoruba kan to wa niluu oyinbo tiẹ pe oun, to sọ fun oun pe oun fẹẹ wale, toun si sọ fun un pe ko ma wulẹ ṣe iyọnu nitori owo baalu, nitori ko fi bẹẹ si owo lati fun un, ṣugbọn ọkunrin na sọ pe ọmọ Yoruba loun, ọrọ to si wa nilẹ yii, ọmọ Yoruba lo kan, o ni oun maa waa darapọ mọ wọn.

O ni pẹlu eleyii, ireti wa pe didun lọsan yoo so.

Leave a Reply