Awọn adari ẹgbẹ APC l’Abuja gbe isakoso ẹgbẹ le Akala lọwọ nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi nnkan ko ṣe ṣenuure fun alaga tẹlẹ fẹgbẹ oṣelu All Progessives Congress, APC, nipinlẹ Ọyọ, Oloye Akin Ọkẹ, akitiyan baba naa lati jẹwọ ara ẹ gẹgẹ bii afọbajẹ ninu ẹgbẹ ọhun ko seso rere.

Eyi ko ṣẹyin bi Oloye Ọkẹ ṣe kọwe ẹsun si igbimọ apapọ ẹgbẹ APC to n gbọ awuyewuye to suyọ nibi awọn idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye kaakiri orileede yii, pe ki wọn gba diẹ ninu awọn eeyan oun to dupo alaṣẹ ẹgbẹ naa wọle, ki wọn jọ maa ṣejọba pẹlu awọn ti ẹgbẹ dibo yan, ṣugbọn ti awọn igbimọ naa sọ pe Ọtunba Adebayọ Alao-Akala ni ko lọọ ba sọrọ.

Ṣe kidaa awọn ọmọ ẹgbẹ to dupo lati igun Ọtunba Akala nikan ni nigbimọ eleto idibo kede gẹgẹ bii awọn to wọle idibo, ti wọn yoo si maa ṣakoso ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ.

Ṣaaju eto idibo ọhun ni Oloye Ọkẹ ti kegbajare pe awọn kan ti n gbiyanju lati gbọna ẹyinkule yan awọn oloye ẹgbẹ tuntun ninu idibo to n bọ lọna nigba naa.

Bakan naa ni inu baba yii atawọn agbaagba ẹgbẹ ọhun kan ko dun si pe ki Akala, ẹni ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ APC latilẹ, to jẹ pe latinu ẹgbẹ oṣelu ADP lo ti wa, maa la le awọn ti awọn ti n jiya ẹgbẹ naa bọ latilẹ lọwọ.

Nitori naa, nigba ti awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa gbe igbimọ apẹtusaawọ eto idibo kalẹ lati wọna ti wọn le gba pin ipo oloye ẹgbẹ laarin awọn agbaagba ẹgbẹ naa tinu n bi, lọgan ni baba naa kọwe si igbimọ yii pe wọn niṣẹ lati ṣe ni ipinlẹ Ọyọ naa.

Ṣugbọn ALAROYE hu u gbọ pe ibi ti Oloye Ọkẹ atawọn eeyan rẹ foju si, ọna ko gbabẹ lọ pẹlu bi awọn igbimọ naa ṣe sọ fun alaga tẹlẹ fẹgbẹ APC  yii pe Ọtunba Akala to kọyin si yẹn gan-an ni ko lọọ ba sọrọ nitori awọn ko le mu ayipada kankan ba awọn oloye tuntun ẹgbẹ wọn laijẹ pe ọmọ Ogbomọṣọ to ti ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ yii lọwọ si i.

Leave a Reply