Awọn adigunjale fọ banki n’Ilara-Mọkin, wọn yinbọn pa eeyan mẹta

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹta ni wọn pade iku ojiji lasiko tawọn adigunjale kan fọ banki UBA to wa niluu Ilara-Mọkin, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe oniroyin kan to jẹ agbẹnusọ fasiti aaladaani kan to wa niluu Ilara, Ọgbẹni Olubunmi Afuyẹ, ọlọpaa kan, pẹlu ẹnikan to wa lori ọkada lawọn adigunjale ọhun yinbọn pa lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ.

Obitibiti owo ti ko sẹni to ti i mọ iye rẹ ni wọn lawọn agbebọn ọhun ko ninu banki naa laarin isẹju diẹ ti wọn fi ṣọṣẹ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni  ni iwadii awọn ti bẹrẹ lori rẹ.

Leave a Reply