Awọn adigunjale ji mọto Toyota oniroyin gbe l’Ondo

Faith Adebọla

Awọn afurasi adigunjale ti ji ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry, eyi tawọn eeyan n pe ni pẹnsu, gbe. Ọkunrin oniroyin kan to fi ilu Ondo ṣebugbe lo ni ọkọ ọhun.
Ibi to gbe ọkọ ọhun si ni ile rẹ to wa ni Ojule igba, lọna Ademulẹgun, niluu Ondo, nipinlẹ Ondo, lawọn gbewiri ẹda naa ti ji i gbe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii.
Nọmba ọkọ alawọ eeru naa ni: NND 399 AE, Nọmba Chassis ẹ ni: 4TIB922KXVU818913.
Ẹnikẹni to ba kẹẹfin mọto naa le tete fi to agọ ọlọpaa to ba wa nitosi leti, tabi pe nọmba yii: 08032621410

Leave a Reply