Awọn adigunjale kọ lu ileeṣe redio Yinka Ayefẹlẹ n’Ibadan, wọn ko dukia rẹpẹtẹ lọ

Faith Adebọla

Awọn adigunjale mẹta kan ti kọ lu ileeṣẹ redio Fresh FM, to wa niluu Ibadan, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin yii, ọpọ dukia ati irinṣẹ ileeṣẹ redio naa ni wọn ji ko.
Ba a ṣe gbọ, gende mẹta lawọn gbewiri ẹda naa, wọn ni niṣe ni wọn rọra wọle bii kọsitọma, nnkan bii aago mẹfa aabọ owurọ ni wọn wọle sileeṣẹ redio naa to wa ni Yinka Ayefẹlẹ Music House, nidojukọ ileepo Conoil to wa lagbegbe Challenge, lọna marosẹ Eko s’Ibadan, ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.
Eto n lọ lori afẹfẹ lọwọ lasiko ti wọn de, ni wọn ba yọbọn sawọn oṣiṣẹ, kia ni wọn dabaru eto redio naa.
Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣe redio naa, Ọgbẹni Kenny Ogunmilọrọ, to kọ ọrọ nipa iṣẹlẹ yii sori opo ayelujara tuita rẹ, sọ pe:
“Ko si ibi to laabo mọ o, titi kan awọn ileeṣẹ redio, eto aabo ti mẹhẹ lorileede yii. Awọn adigunjale mẹta ṣakọlu sileeṣẹ redio wa laaarọ yii, ni nnkan bii aago mẹfa kọja iṣẹju mẹẹẹdogun. Gbogbo foonu, ẹrọ agbeletan, kaadi ATM ati awọn irinṣẹ wa ni wọn ji lọ, ṣugbọn wọn o ṣe ẹnikẹni leṣe. O baayan ninu jẹ gan-an.”
Ileeṣe ọlọpaa ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ yii titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ. Ṣugbọn ileeṣẹ redio naa ti ṣiwọ igbohunsafẹfẹ na.

Leave a Reply