Awọn adigunjale kọ lu ọkọ agboworin l’Emure

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọlọpaa kan la gbọ pe o fara gbọta lasiko tawọn adigunjale ṣe akọlu si ọkọ agboworin banki kan lagbegbe Emure-Ile, nijọba ibilẹ Ọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe awọn agbebọn ọhun lo anfaani awọn bọmbu ti wọn mọ ṣoju ọna marosẹ to gba ilu Emure kọja lati gẹgun de ọkọ agboworin naa, lai mọ pe ko sowo kankan ninu rẹ.

Lojiji ni wọn lawọn ẹruuku ọhun ṣina ibọn bolẹ, tawọn ọlọpaa ti wọn n tẹle ọkọ banki naa si da a pada fun wọn loju-ẹsẹ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ yan nipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loootọ lawọn adigunjale ọhun ṣe ọlọpaa kan leṣe lasiko ti wọn jọ kọju ija sira awọn, ṣugbọn idunnu lo jẹ pe wọn ko rowo kankan gbe ninu ọkọ naa.

O ni loju-ẹsẹ lawọn ti gbe ọlọpaa to fara pa lọ sileewosan kan ti oun forukọ bo laṣiiri fun itọju to peye

 

Leave a Reply