Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, ni awọn ẹlẹwọn mẹta ti wọn fi ẹsun idigunjale kan Umaru, Ṣẹgun Nasiru ati Isa Usman, sa lọ lọgba ẹwọn to wa ni agbegbe Mandala, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti wọn si ti fi awọn to n sọ ọgba ẹwọn naa sinu idaamu bayii.
ALAROYE, gbọ pe Umaru ni wọn ti dajọ iku fun fun ẹsun idigunjale, bakan naa ni wọn fi ẹsun idigunjale kan Ṣẹgun ati ekeji ẹ, ṣugbọn wọn duro de idajọ ile-ẹjọ. Awọn mẹtẹẹta ni wọn ti sa lọ bayii. Iroyin ta a gbọ ni pe awọn ẹlẹwọn ọhun rẹ irin to wa lẹnu iloro ni wọn fi raaye sa lọ
Agbẹnusọ ajọ to n mojuto ọgba ẹwọn nilẹ yii, Ọgbẹni Francis Enobore, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn o ni oun o le sọ ni pato bi iṣẹlẹ naa ti waye. O ni lẹyin iwadii lawọn yoo ṣe ẹkunrẹrẹ alaye lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Titi digba ta a n ko iroyin yii jọ, inu idaamu nla lawọn to n ṣọ ọgba ọhun wa bayii.