Awọn adigunjale ni Kọlapọ n f’ọkada ẹ gbe n’Ikire tọwọ fi tẹ ẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti oni nnkan, eyi lo difa fun bi ọwọ ṣe tẹ awọn ọdọkunrin meji kan ti wọn ti fi ọpọlọpọ igba yọ awọn eeyan ilu Ikire, nipinlẹ Ọṣun lẹnu.

Korede Yẹkini, ẹni ọdun mẹtalelogun, ni Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, sọ pe ọwọ tẹ lẹyin ti awọn kan lọọ fẹjọ sun lagọọ ọlọpaa ilu Ikire pe awọn adigunjale mẹrin ka awọn mọle loru ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Ọlọkọde ṣalaye pe awọn adigunjale naa gba owo, foonu atawọn nnkan miiran lọwọ awọn eeyan agbegbe Atoto, niluu Ikire.

Lọgan lawọn ọlọpaa fọn sita, gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe sọ, ọwọ si tẹ Yẹkini Korede, ẹni to mu wọn lọ sile Kọlapọ Akanmu toun jẹ ọlọkada.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Korede ṣalaye pe iṣẹ pako loun n ṣe, o ni atijẹ-atimu lo sun oun dedii iṣẹ ole ati pe ko pẹ rara ti oun darapọ mọ wọn ti ọwọ fi tẹ oun.

Ninu awijare tirẹ, Kọlapọ ṣalaye pe iṣẹ ọkada loun n ṣe, o ni ṣe ni Korede maa n pe oun lori foonu; yala nidaaji tabi lalẹ, lati gbe oun lọ sawọn agbegbe kan niluu Ikire.

O ni oun ko mọ pe iṣẹ adigunjale lawọn eeyan naa n ṣe, ṣe loun ro pe iṣẹ awakọ tirela ni wọn n ṣe, ati pe laarin ẹgbẹrun mẹta si ẹẹdẹgbẹta naira ni wọn maa n fun oun ni gbogbo igba ti oun ba gbe wọn.

Ṣugbọn kọmiṣanna ọlọpaa sọ pe ṣe ni Kọlapọ to jẹ ọmọ bibi ilu Ikire lẹdi apo pọ mọ Stephen Igeh ati ọkunrin kan to n jẹ Afeez pẹlu awọn mi-in lati Ibadan lati digun ja awọn araalu lole.

Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni ibọn, ada, foonu oriṣiiriṣii mẹfa, ẹgbẹrun mẹta naira, ẹgba-ọrun, ati aago-ọwọ.

O ni ni kete tiwadii ba ti pari ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply