Awọn adigunjale pa ọlọdẹ ni Sango, wọn tun gba mọto meji

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ode ro laaarọ kutu Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu karun-un, yii lagbegbe Ipamẹsan, ni Sango. Ikọ adigunjale kan lo ya wọ ile ikẹru-si kan nibẹ, wọn yinbọn pa ọlọdẹ to n ṣọ ile naa, wọn si tun gba mọto ayọkẹlẹ meji lọwọ eeyan meji. Wọn dalẹ ru gidi kọwọ ọlọpaa too tẹ ọkunrin ti ẹ n wo yii,  Henry Obe, ọkan lara ikọ apanilẹkun naa ni i ṣe.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa lede ṣalaye pe awọn kan lo pe teṣan ọlọpaa Sango pe awọn adigunjale ti n dan mẹwaa wo n’Ipamẹsan, wọn si ti fọ ile ikẹru-si kan.

Nigba tawọn ọlọpaa debẹ ni wọn ri i pe wọn ti ko ẹru to wa nile ikẹru-si naa, lẹyin ti wọn yinbọn fun ọlọdẹ to n ṣọ ibẹ. Awọn eeyan pada gbe ọlọdẹ naa lọ sọsibitu, ṣugbọn niṣe lo dagbere faye.

Yatọ si ọlọdẹ ti wọn pa, wọn tun gba mọto Lexus RS 330 ti nọmba ẹ jẹ FKJ 691 FW lọwọ Dosumu Kazeem, wọn si gba Toyota Matrix ti nọmba ẹ jẹ MUS 835 FW lọwọ Ibrahim Lateef.

Awọn ọlọpaa le awọn ole yii, ikọ adigunjale naa ko si duro, wọn n sa lọ ni. Nigba ti wọn de Jọju, ti wọn ri i pe awọn ọlọpaa ko pada, ti ko si sọna mi-in mọ, awọn ẹruuku naa duro, wọn doju ija kọ awọn ọlọpaa bi Oyeyẹmi ṣe ṣalaye, wọn si jọ bẹrẹ si i yinbọn sira wọn.

Ọwọ ọlọpaa ju tiwọn lọ ni wọn ṣe fi mọto meji ti wọn ja gba naa silẹ, ti wọn sa lọ. Afi Henry Obe yii nikan ni ko ribi sa gba, ti awọn ọlọpaa ri mu ṣinkun.

Eyi lawọn ẹru ti awọn ọlọpaa ri gba lọwọ ole kan to ṣẹku yii: Ibọn gigun kan, kọmputa alaagbeletan mọkanlelogoji, ẹrọ ti wọn fi n wo fiimu ninu ile meji, foonu meji, mọto meji ti wọn ja gba yii ati kọmputa mẹta.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn gbe eyi tọwọ ba lọ sẹka iwadii, ki wọn si wa awọn yooku rẹ to sa lọ ri.

Leave a Reply