Awọn adigunjale to yinbọn pa oṣiṣẹ ileepo Akurẹ d’ero ile-ẹjọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Meji ninu awọn adigunjale to yinbọn pa oṣiṣẹ ileepo kan lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹfa ọdun yii ti foju bale-ẹjọ majisreeti to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ.

Emmanuel James, ẹni ogun ọdun, Wisdom Richard ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn atawọn mi-in ti wọn ti salọ ni wọn fẹsun kan pe wọn lọ sile-epo Farbas to wa l’Alagbaka ni nnkan aago mẹsan-an alẹ ọjọ naa nibi ti wọn ti ṣe ẹnikan leṣe ti wọn si tun yinbọn pa oṣiṣẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Bankọle Abdullahi.

Ọlọpaa agbefọba Onheninhen Augustine ninu ọrọ rẹ ni ẹsun mẹrẹẹrin ti wọn fi kan awọn olujẹjọ naa tako ofin ipinlẹ Ondo to lodi si iwa idigunjale.

Augustine ni iwadii tawọn ọlọpaa ṣe fidi rẹ mulẹ pe ogbologboo ati akọsẹmọsẹ adigunjale to n yọ awọn eeyan ilu Akurẹ lẹnu lawọn mejeeji. O bẹ kootu ọhun lati paṣẹ fifi awọn mejeeji pamọ sọgba ẹwọn na titi ti imọran yoo fi wa lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

Niwọn igba ti Amofin E.O. Owanei to jẹ agbẹjọro wọn ko ti tako aba yii, loju ẹsẹ ni Adajọ Abilekọ O.R. Yusuf ti gba ẹbẹ agbefọba wọle. O paṣẹ poe kawọn ọdaran naa wa ni ahamọ awọn ọlọpaa titi di inu oṣu kọkanla ọdun ta a wa yii.

 

Leave a Reply