Awọn adigunjale ya wọ ileeṣẹ redio ijọba ipinlẹ Ọyọ, wọn ji dukia olowo nla lọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu aibalẹ ọkan lawọn ara ìletò Gàm̀bàrí, nilẹ Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, wa bayii pẹlu bi awọn adigunjale ṣe ya wọ abule ọhun tibọntibọn, ti wọn si ji ọpọlọpọ dukia lọ.

Ajilete FM, to jẹ ẹka ileeṣẹ igbohunsafẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Broadcasting Corporation of Oyo State (BCOS), labule Gàm̀bàrí, lawọn amookunṣika naa ti ṣiṣẹ laabi ọhun loru Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, mọju ọjọ Ẹti, iyẹn Furaidee, ọjọ kẹrindilogun (23), oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ta a wa yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọdẹ to n ṣọ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ọhun lawọn adigunjale yii kọkọ doju ija kọ, ti wọn fi okun di i lọwọ ati ẹsẹ lẹyin ti wọn ti kọ lu u bii asọ ofi, ti wọn si fi idi ibọn wọn run baba ẹni aadọrin ọdun (70) naa lárùn-ún-kì.

Lẹyin naa ni wọn wọ’nu ile ti wọn n ṣe ẹrọ amunawa lọjọ si nileeṣẹ naa, ti wọn si ge waya to mu ina ẹlẹntiriiki wọn ara ẹrọ igbohunsafẹfẹ wọn nileeṣẹ naa lọ.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Kabir Kasali, ti i ṣe olori ẹka imọ ẹrọ l’Ájílété FM, ṣe fidi ẹ mulẹ fun akọroyin wa, yatọ si waya ina ti wọn ge lọ pẹlu awọn dukia mi-in, awọn alọ-kólóhun-kígbe ọhun tun ji ẹrọ ti wọn fi n gba iroyin lati olu ileeṣẹ wọn ni BCOS, n’Ibadan, gbe lọ.

Bakan naa ni wọn gbe alupupu baba ọdẹ naa lọ lẹyin ti wọn lu baba onibaba ṣe leṣe tan.

Awọn oṣiṣẹ to fẹẹ wọ iṣẹ laaarọ ọjọ keji iṣẹlẹ yii l’ALAROYE gbọ pe wọn tu baba naa nigbekun, ti wọn si gbe é lọ sileewosan aladaani kan ti wọn pe ni Oluwakẹmi Clinic, ni Gambari níbẹ.

Latari ijanba buruku tawọn adigunjale ọhun ṣe nibẹ, ko ti i ṣee ṣe fun ileeṣẹ redio ọhun lati maa gbohun safẹfẹ pada titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

 

Leave a Reply