Awọn adigunjale yinbọn lu gbajumọ oniṣowo, wọn tun ji miliọnu mẹjọ naira rẹ lọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gbajumọ alagbata epo rọbi, Jimọh Wẹrẹwẹrẹ, lawọn adigunjale ti ṣe akọlu si ni ilu Gure, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara. Wọn fi ọta ibọn da ọgbẹ si i lara, wọn tun ji miliọnu mẹjọ naira rẹ gbe lọ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnuṣọ ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ naa, Babawale Zaid Afolabi, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, lo ti ṣalaye pe awọn adigunjale bii marun-un ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro ni wọn ṣe akọlu si gbajumọ oniṣowo epo rọbi kan, Jimọh, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide.

A gbọ pe wọn ti n ṣọ ọ lati ọjọ pipẹ ni ilu Gure, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, wọn ṣe e basubasu, wọn tun ji owo rẹ gbe sa lọ.

O tẹsiwaju pe, ko pẹ pupọ ti wọn yinbọn lu onisowo ọhun tan ni ikọ ṣifu difẹnsi debi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn adigunjale ọhun ti na papa bora, wọn si fi ọkunrin onisowo yii sinu agbara ẹjẹ. Iwadii fi han pe wọn ji miliọnu mẹjọ CFA, ti i ṣe miliọnu mẹjọ naira owo ilẹ wa, to jẹ ti onisowo naa lọ.

O fi kun un pe Jimọh ti n gba itọju bayii ni ileewosan ti wọn ko darukọ, ti ikọ ṣifu difẹnsi ati ileesẹ ọlọpaa si ti ṣabẹwo si i. Bakan naa, Afọlabi ni awọn ti n sa ipa awọn lati wa awọn ọdaran naa lawaari, kawọn si fi panpẹ ofin gbe wọn.

Leave a Reply