Awọn adigunjale yinbọn pa oniṣowo n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Awọn adigunjale ẹlẹni meji kan ti ran gbajumọ oniṣowo bàtà nigboro Ibadan lọ sọrun apapandodo.

Ọkunrin naa, Ọgbẹni Afuyẹ, lo n ti ṣọọbu to ti n taja bọ lọjà Ogunpa, n’Ibadan, ti awọn adigunjale ẹlẹni meji ọhún fi dá a lọna nigba to ku diẹ ko délé nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ijẹta.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọkada lawọn adigunjale naa gun ti wọn fi já ọkada gba mọ ọkunrin oniṣowo náà lọwọ laduugbo ti wọn n pe ni Baba Sala, ni Sango, n’Ibadan.

Olugbe adugbo ọhún kan ti iṣẹlẹ yii ṣoju ẹ ṣalaye f’ALAROYE pe “Lẹyin ti ọkan ninu awọn ole yẹn gba ọkada lọwọ ẹ (Afuyẹ) lo bẹrẹ si i sare tẹle wọn, to sí n pariwo ole le wọn lori.

“Nigba yẹn lọkan ninu awọn ole yẹn fa ibọn yọ, to sí yín in mọ ọ nigbaaya.

“Ariwo ti baba yẹn n pa le awọn adigunjale yẹn lori ni ko jẹ ki wọn le gbé ọkada rẹ lọ. Ẹ̀gbẹ́ maṣíìnì ẹ naa lo ṣubu si to fi kú nitori loju ẹsẹ naa nibọn ti wọn yín mọ ọn ti pa a.”

ALAROYE gbọ pe inu oyun ni iyawo baba ti wọn yinbọn pa ọhun wa, asiko to yẹ ko bímọ sì ti fẹrẹ pe. Idi ree ti awọn alabaagbe ẹ ko fi ti i mọ bi wọn ṣe le tufọ iku ọkọ ẹ fún un titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, fidi ẹ mulẹ pe ni kete ti wọn fi iṣẹlẹ idigunjale yii to awọn leti lawọn ọlọpaa lati teṣan ti yara lọ sibẹ lati dẹkun iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe wọn yi yinbọn pa ọkunrin naa bo tilẹ jẹ pé wọn kò rí ọkada rẹ gbe lọ.

O ni awọn agbofinro ni wọn palẹ oku ọkunrin naa mọ pẹlu ọkada ẹ, ti wọn gbé alupupu lọ sí teṣan wọn, ti wọn sì lọọ tọju oku ọkunrin oniṣowo yii pamọ sì yara ti wọn n ṣe oku lọjọ sí l’Adeọyọ Maternity ti i ṣe ileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ.

 

Leave a Reply