Awọn afeeyanṣowo fọ ọmọọdun mọkanla lori, wọn si yọ ọpọlọ ẹ lọ

Faith Adebọla

 Iku oro lawọn amookunṣika ẹda ti wọn fura pe afeeyanṣowo ni wọn, fi pa ọmọdekunrin ẹni ọdun mọkanla kan, Muhammed Yunusa, niṣe ni wọn fọ ọmọ naa lori, ti wọn si yọ ọpọlọ ẹ lọ.

Iṣẹlẹ yii la gbọ po waye lọjọ Aiku, Sannde,  yii, laduugbo Wambai, niluu Bauchi, nipinlẹ Bauchi, lapa Oke-Ọya.

Ba a ṣe gbọ, wọn lawọn ọmọ naa wa lara awọn alumajiri ti wọn maa n tọrọ baara lagbegbe naa, wọn ni niṣe lawọn afurasi ọdaran to ṣiṣẹẹbi ọhun pe meji lara awọn ọmọde ọhun, ti wọn si ṣe bii ẹni fẹẹ fun wọn lowo.

Wọn ni ibi kọlọfin kan ni wọn ti la nnkan mọ ọmọ naa lori, ti wọn fi raaye yọ ọpọlọ rẹ lẹyin to ku tan, ti wọn si ba ẹsẹ wọn sọrọ.

Ọmọ keji ti ori ko yọ lọwọ wọn, Aminu Yusuf, toun jẹ ọmọọdun mejila, lo kegbajare fawọn aladuugbo to wa nitosi, nigba tawọn eeyan yoo si fi debẹ, ọṣẹ ti ṣe, ni wọn ba lọọ fi to ọlọpaa leti, ọmọ naa si ṣalaye bọrọ ṣe jẹ, lawọn agbofinro ba bẹrẹ iwadii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, SP Muhammad Ahmad Wakil, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe nigba tawọn de ibi iṣẹlẹ naa, awọn ba oku ọmọdekunrin ọhun ninu agbara ẹjẹ, wọn ori rẹ ti fọ, wọn si ti yọ ọpọlọ rẹ lọ.

O ni okuta nla ni wọn fi fọ ọmọ naa lori, ki wọn too na papa bora.

Ṣa, wọn  ti gbe oku ọmọde naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba fun ayẹwo.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, Sylvester Abiọdun Alabi, si ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ lati wa awọn ẹni ibi to wa nidii iwa ọdaju yii lawaari tobinrin n wa nnkan ọbẹ, ki wọn le ri pipọn oju ijọba.

Leave a Reply