Awọn afẹmiṣofo da bọọsi elero duro, wọn dana sun ọkọ ati ero ogoji to wa ninu ẹ

Faith Adebọla

Awọn janduku agbebọn tile-ẹjọ ṣẹṣẹ polongo wọn ni afẹmiṣofo ti tun gbọna mi-in yọ pẹlu iwa ọdaju wọn, niṣe ni wọn da bọọsi elero ogoji kan tawọn arinrin-ajo kun inu rẹ fọfọ duro, wọn si da bẹntiroolu sara ọkọ naa, wọn dana si i, wọn si duro ti i titi tọkọ naa atawọn ero inu rẹ fi jona raurau.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Sokoto ṣe fidi ẹ mulẹ, iṣẹlẹ yii waye nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu kejila yii, nitosi abule Gidan Bawa, nijọba ibilẹ Sabon Birni, nipinlẹ Sokoto.

Wọn ni awọn arinrin-ajo naa n lọ sipinlẹ Kaduna ni, wọn lawọn kan lara wọn fẹẹ pada sọdọ awọn mọlẹbi wọn bi wọn ṣe maa n ṣe lọdọọdun lasiko ipari ọdun, ti wọn jọ maa n ṣe pọpọṣinṣin ọdun papọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Sokoto, CP Kamaludeen Okunọla, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lori iṣẹlẹ naa pe eeyan mẹtalelogun ni wọn dana sun mọ mọto naa, o lawọn mẹsan-an fara gbọgbẹ nibi ti wọn ti n sa lọ, wọn si ti wa lọsibitu bayii, nibi ti wọn ti n gba itọju pajawiri lọwọ.

O ni iwadii fihan eeyan ọgbọn lo wa ninu ọkọ naa, ati pe niṣe lawọn agbebọn naa diidi dena de ọkọ ọhun, wọn kọkọ yinbọn si taya rẹ, wọn o si jẹ kawọn eeyan inu rẹ bọọlẹ, ti wọn fi dana sun gbogbo wọn mọnu ọkọ.

O lawọn ti ko ọlọpaa da sita lati maa ṣọ awọn agbegbe to ṣee ṣe kawọn afẹmiṣofo ti tun fẹẹ dana iwakiwa wọn.

Bakan naa ni aṣofin ana nipinlẹ Kaduna, Sẹnetọ Shehu Sanni, kọ ọ sori atẹ fesibuuku lori ẹrọ ayelujara lọjọ Tusidee yii pe: “Eeyan mejilelogoji ni wọn pa nipa ika danu, wọn sun wọn jona nipinlẹ Sokoto lanaa. To ba jẹ labẹ ijọba Jonathan yii, iru iṣẹlẹ yii iba ti da yanpọnyanrin silẹ, tawọn eeyan yoo maa sọrọ nipa ijakulẹ ijọba, ti wọn yoo si maa dẹbi ru iṣejọba radarada pe oun lo fa a.

Awọn ti wọn o le sọrọ soke, ti wọn gbẹnu dakẹ lasiko yii, wọn ko yatọ sawọn ti wọn dagunla, awọn ti wọn si n dagunla ati awọn to wa nidii iru iṣẹlẹ aburu yii, ọgbọọgba ni wọn.

Mi o ti i ri ibomi-in lagbaaye ti ifẹmiṣofo ti di meji eepinni, ti ẹmi eeyan ti di nnkan yẹpẹrẹ, tawọn alaṣẹ o si bikita bii tiwa yii, mo n wa a, mi o ti i ri i. Eyi ga o.

Bẹẹ ni Sẹnetọ Sanni kọ ọ sori ikanni rẹ.

Leave a Reply