Awọn afiniṣowo pa agunbanirọ niluu Abuja, wọn yọ gbogbo ẹya ara rẹ lọ

Monisọla Saka

Ofo nla gbaa leyi jẹ, ọmọbinrin agunbanirọ to sọnu, Stephanie Ṣe-Ember Terungwa, pẹlu nọmba idanimọ FC/21B/5807, ni wọn ti pada ri, ṣugbọn wọn ko ri i laaye, oku rẹ ni wọn ri, bẹẹ ni ẹya ara rẹ ko pe mọ, wọn ti yọ oju ara rẹ atawọn nnkan mi-in kuro lara rẹ. Eyi lo jẹ ki awọn eeyan maa fura pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn afiniṣowo lo pa ọmọbinrin naa.
Awọn ẹbi ọmọbinrin yii ni wọn kegbajare pe awọn n wa ọmọ awọn, Terungwa, ti wọn ri kẹyin ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, lagbegbe Lokogoma, l’Abuja.
Ẹgbọn ẹ ọkunrin, Richard Lorliam, ṣalaye pe wọn ji oun atọmọ ẹ ọkunrin to jẹ ọmọ ọdun kan gbe lakooko to n bọ nibi iṣẹ idagbasoke ilu (CDS) tawọn agunbanirọ maa n ṣe. O ni wọn pada ri ọmọ ọhun ṣugbọn awọn ṣi n wa iya ẹ.
Stephanie to n gbe niluu Makurdi, nipinlẹ Benue, lọ kekọọ gboye ninu imọ Microbiology nileewe Fasiti JS Tarka, to wa ni Markurdi, nipinlẹ Benue, to si n sin ilẹ baba ẹ lọwọ l’Abuja, nigba ti iṣẹlẹ laabi ọhun ṣẹlẹ.
Amọ ṣa o, ninu atẹjade olori awọn akẹkọọ nileewe ọhun, o ṣalaye pe wọn pada ri oku ẹ, nitori pe inu aṣọ agunbanirọ to wọ naa ni wọn pa a si, wọn si ti yọ awọn nnkan ti wọn fi n da ọmọbinrin mọ gbogbo to wa lara ẹ.
Iku ọmọbinrin yii ti da rogbodiyan silẹ lori ẹrọ ayelujara, awọn ọdọ si ti n beere fun idajọ ododo. Pupọ ninu wọn lo n pariwo pe asiko ibo ta a wọ lọ yii lo da gbogbo eleyii silẹ, awọn mi-in tilẹ sọ pe kijọba fopin si eto isinru ilu ọhun.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati foju awọn aṣebi ọhun lede, ki wọn le ṣedajọ to yẹ fun wọn.

Leave a Reply