Awọn afọbajẹ pariwo: Ẹ gba wa o, Oluwoo ti dẹ awọn tọọgi si wa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, ni ina ọrọ ọhun ru jade, ọjọ yẹn ni mejila lara awọn afọbajẹ ilu Iwo fi ọwọ si iwe kan, wọn si mu un lọ sọdọ gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla.

Ohun to wa ninu lẹta naa ni pe ki gomina ba awọn yọ Oluwoo, Ọba Abdulrasheed Adewale, lori oye. Ẹsun mọkanla ni wọn ka si ọba yii lẹsẹ, wọn ni ọba naa ko yẹ nipo nitori oniruuru iwa idojuti to n hu kaakiri, eyi to n ba orukọ ilu naa jẹ.

Lara awọn ti wọn fọwọ si iwe naa ni Oloye Raufu Murana Olorunlampe (Balogun), Oloye Fatai Alani Olaoye (Onto), Oloye Yekeen Bello Orobimpe (Oosa), Oloye Sunday Oyetunde Oyeniyi (Olosi), Oloye Ganiyu Kazeem Ayinde (Jagun) ati Oloye Moses Akanmu Ajao (Ọlọya).

Awọn to ku ni Oloye Baṣiru Ajani Akinṣọla (Olukọtun), Oloye Lamidi Mọrufu Oyeleke (Ọḍọfin), Oloye Suraju Bello (Onju), Oloye Lateef Ishọla (Agoro), Oloye Moshood Amọo (Aṣape), Oloye Rasaki Akanmu Tijani (Olukosi) ati Oloye Amao Ọlaoṣebikan Taiwo (Aro).

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Ọba Adewale ni pe o ba ọba ẹgbẹ rẹ ja titi ti igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ọṣun fi da a duro fodidi oṣu mẹfa. Wọn ni Oluwoo ti Iwo-Oke tun ti figba kan gbe e lọ sile-ẹjọ, ṣugbọn ti ko lọ, to si jẹ pe awọn eeyan bii Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo yọ ọ lọwọ aṣẹ ti kootu pa.

Wọn ni lọdun 2016, Ọba Adewale tun sọ pe gbogbo ọmọ Yoruba lo le di Ọọni ti Ifẹ, eleyii to le da wahala silẹ nilẹ Yoruba. Bakan naa lo tun gba iṣẹ Imaamu Agba ilu Iwo ṣe lọjọ ọdun Ileya lọdun naa.

Awọn afọbajẹ fi kun ọrọ wọn pe Oluwoo tun ti figba kan sọrọ to le da wahala silẹ niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ. Wọn lo sọ ninu ifọrọwerọ kan pe ilu Iwo lo maa n yan ẹni ti yoo jẹ Olubadan.

Wọn ni ija igboro wa ninu ẹjẹ Oluwoo, ko si si eeyan nla nla ti ko ti i ba ja tan. Lara wọn ni Ọọni ti Ifẹ, Alaafin ti Ọyọ, Ọrangun ti Ila, Oloye Abiọla Ogundokun, Imrah Adio ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gomina Gboyega Oyetọla

Ju gbogbo rẹ lọ, awọn afọbajẹ yii sọ pe o jẹ nnkan ibanujẹ fun awọn pe ẹni to ti ṣẹwọn ri lorileede United States of America (USA) ati Canada ni Oluwoo.

Wọn ni ki Gomina Oyetọla gba ilu Iwo lọwọ idojuti ti Ọba Adewale n mu ba a nipa yiyọ ọ nipo ọba to wa ko too di pe yoo ba ilu Iwo jẹ.

Ṣugbọn ọrọ naa ko ti i balẹ ti Akọwe iroyin Ọba Adewale, Alli Ibrahim, fi fun awọn baba naa lesi. O ni atamọ lasan ni ọrọ awọn baba naa ati pe ariwo ọja lasan ni wọn n pa, eleyii ti ko si le tu irun kankan lara Oluwoo.

Alli ṣalaye pe ọmọọba kan to du ipo Oluwoo pẹlu Ọba Adewale Akanbi lo wa nidii wahala naa, o ni wọn n ṣe bẹẹ lati le jẹ ki awọn eeyan ro pe ko si alaafia niluu Iwo, ṣugbọn ero wọn ko le jọ.

O ni ko si bi idunkukulaja naa ṣe le le to, ko le di awọn iṣẹ rere ti Oluwoo n ṣe fun awọn eeyan ilu naa lọwọ rara, ati pe ẹni to n lo awọn oloye oun lati ṣiṣẹ tako oun kan n ṣe e lasan ni, ṣe ni ko lọ gba fun Ọlọrun.

Lọjọ keji, iyẹn Ọjọbọ, Tọsidee, Igbakeji Oluwoo, to si jẹ olori awọn afọbajẹ niluu Iwoo, Oosa ti ilu Iwo, Oloye Yekeen Bello, ba ALAROYE sọrọ nile rẹ, o ni ọrọ rirun gbaa ni Alli sọ lorukọ Oluwoo, ati pe ti awọn ba fẹẹ gba owo lọwọ ẹnikẹni lati lo awọn tako Oluwoo, ọrọ naa ko ni i le to bayii.

Oloye Bello ni “Nitori iwa ati iṣe Oluwoo lo jẹ ka kọ iwe ẹhonu naa si gomina. Ihuwasi rẹ ti n ko idojuti ba ilu Iwo, ti ẹ ba ri nnkan ti awọn eeyan maa n sọ nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara, ẹ maa mọ pe o buru jai.

“Nigba ti ọba ko ba ka awọn ijoye si, ti ko ka awọn agbaagba si, ki lẹ ro pe o le ṣẹlẹ? A ti gbiyanju pupọ lati mu iwa rẹ mọra, ṣugbọn a ko le tẹsiwaju mọ bayii, a ti gba a nimọran, a pe e jokoo, sibẹ, ko ni i gbọ, idi niyẹn ti awa afọbajẹ fi pinnu pe a gbọdọ gbe igbesẹ kan.

“Fun apẹrẹ, Ọlaoluwa ati Ayedire wa labẹ ilẹ Iwo, ṣugbọn awọn da loni-in? Ṣe ohun to bojumu ni ki awọn igbimọ lọbalọba da ọba duro gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ si Oluwoo? Aanu Alli ṣe mi pẹlu irọ buruku to n pa kaakiri, a si ti fun un ni ọjọ meje lati sọ ẹni to sọ pe o gbe owo fun wa lati maa daamu Oluwoo, lai jẹ bẹẹ, yoo ba wa ni kootu.

“Dipo ko fun awa oloye ni ẹtọ wa ninu alokesan to n gba loṣooṣu, ṣe lo sọ pe ka lọọ wa iṣẹ ṣe. O ni ọba nikan lo ni alokesan, ẹrin pa mi, ṣe ara-oko lo pe wa ni? Ki odidi oloye maa mu ẹgbẹrun mẹta, ẹgbẹrun mẹrin lọ sile loṣooṣu, o ṣe ni laaanu.

“Ko too di pe a fi Adewale jọba, yatọ si pe ko gbe ninu ilu, ṣe lo dibọn fun wa, iwa oniwa lo n hu, o fiwa pamọ fun wa, ṣugbọn nitori pe ọrẹ lemi ati baba rẹ, mo ti i lẹyin. Nigba to fẹẹ joye, mo ti ra bulọọku ti mo fẹẹ fi kọle silẹ, ṣugbọn mo na owo yẹn lori ọrọ oye ọba yii ni, ti bulọọku si ṣofo, ṣugbọn bayii, emi ni olori awọn ọta rẹ.

“Awa mẹrinla ni afọbajẹ, ẹni kan ti ṣalaisi laarin wa, a ko si mu iwe lọ sọdọ ẹni kẹtala nitori idi pataki to han si wa. Ohun ti a fẹ bayii ni pe ki gomina ba wa yọ Ọba Adewale nipo, ọrọ rẹ ti su wa”

ALAROYE gbiyanju lati ba ẹni ti Oluwoo sọ pe o ba oun du ipo ọba, Alhaji Abdulazeez Inaọlaji, sọrọ lori ẹsun ti Oluwoo fi kan an pe oun lo wa nidii igbesẹ awọn afọbajẹ sọrọ, ṣugbọn pabo lo ja si. Awọn ti wọn sun mọ baba naa jẹ ko di mimọ pe o ṣee ṣe ko jẹ nitori ẹjọ to wa ni kootu ni baba naa ko ṣe fẹẹ ba awọn oniroyin sọrọ.

Ooni Adeyẹye Ogunwusi

Ṣugbọn Oloye Sunday Oyeniyi, Olosi ti ilu Iwo, ẹni to jẹ afọbajẹ kẹtala ti ko sọrọ ni tiẹ sọ pe ko ṣee ṣe lati rin ki ori ma mi. O ni oun gbagbọ pe Ọlọrun nikan lo le fi ọba jẹ, Oun nikan naa si lo le yọ ọba loye, ati pe oun ko mọ nnkan kan nipa iwe ti awọn afọbajẹ yooku mu lọ sọdọ gomina.

Oloye Oyeniyi waa rọ Oluwoo lati tubọ ni ikomọra, ko yago fun nini ọta kun ọta, bẹẹ lo si ni Ọlọrun nikan ni gbogbo ilu gbọdọ ke pe bayii lati da si ọrọ naa.

Bo ṣe di ọjọ Ẹti, Furaidee, ni awọn afọbajẹ mejila yii gba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun lọ, wọn wọ Oluwoo lọ si kootu, wọn ni ko gbọdọ yọ awọn, bẹẹ ni ko gbọdọ fi ẹlomi-in rọpo awọn gẹgẹ bii afọbajẹ ati oloye.

Ninu iwe ipẹjọ naa to ni nọmba HIW/M.18/2020, eleyii ti Oosa ṣebura le lori pẹlu agbẹjọro wọn, John Enworo, ti ALAROYE si ri lọjọ Aiku, Sannde, ni wọn ti sọ pe lẹyin ti awọn kọ iwe iyọnipo Oluwoo si gomina ni ọba naa dẹ awọn tọọgi si awọn, inu ibẹrubojo ni gbogbo awọn si wa latigba naa.

Oosa fi kun ọrọ rẹ ninu iwe ipẹjọ naa pe Oluwoo ti ranṣẹ si gbogbo awọn agboole awọn afọbajẹ naa lati fi orukọ ẹlomi-in ranṣẹ, eleyii ti yoo fi rọpo awọn afọbajẹ ti wọn fẹ yọ ọ nipo.

Idi niyi ti wọn fi sa di kootu lati da Oluwoo duro ninu igbesẹ to fẹẹ gbe. Bi ẹjọ naa ba si ṣe n lọ si, ALAROYE yoo maa fi to yin leti.

Leave a Reply