Awọn afọbajẹ yari n’Iwoo, wọn l’Oluwoo gbọdọ kuro nipo ọba

Florence Babasola

Awọn afọbajẹ niluu Iwo ti kọ iwe ẹsun ranṣẹ si Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, pe ko rọ ọba ilu naa, Adewale Abdulrasheed Akanbi, loye.

Ninu lẹta ti wọn fi le gomina lọwọ ni ọjọ Iṣẹgun, Tusifee, ọsẹ yii ni wọn ti ka ẹsun mẹtala si Oluwoo lẹsẹ. Wọn ni ọba naa ko yẹ lati maa jẹ Oluwoo pẹlu oniruuru iwa idojuti to n hu kaakiri nipasẹ eyi to n ba orukọ ilu naa jẹ.

Lara awọn ti wọn fọwọ si iwe naa ni Oloye Raufu Murana Olorunlampe (Balogun), Oloye Fatai Alani Olaoye (Onto), Oloye Yekeen Bello Orobimpe (Oosa), Oloye Sunday Oyetunde Oyeniyi (Olosi), Oloye Ganiyu Kazeem Ayinde (Jagun) ati Oloye Moses Akanmu Ajao (Ọlọya).

Awọn to ku ni Oloye Baṣiru Ajani Akinṣọla (Olukọtun), Oloye Lamidi Mọrufu Oyeleke (Ọḍọfin), Oloye Suraju Bello (Onju), Oloye Lateef Ishọla (Agoro), Oloye Moshood Amọo (Aṣape), Oloye Rasaki Akanmu Tijani (Olukosi) ati Oloye Amao Ọlaoṣebikan Taiwo (Aro).

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Ọba Adewale ni pe o ba ọba ẹgbẹ rẹ ja titi ti igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ọṣun fi da a duro fodidi oṣu mẹfa. Oluwoo ti Iwo-Oke tun ti figba kan gbe e lọ sile-ẹjọ ṣugbọn ti ko lọ, to si jẹ pe awọn eeyan bii Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo yọ ọ lọwọ aṣẹ ti kootu pa.

Wọn ni lọdun 2016, Ọba Adewale tun sọ pe gbogbo ọmọ Yoruba lo le di Ọọni ti Ifẹ, eleyii to le da wahala silẹ nilẹ Yoruba. Bakan naa lo tun gba iṣẹ Imaamu Agba ilu Iwo ṣe lọjọ ọdun Ileya lọdun naa.

Awọn afọbajẹ fi kun ọrọ wọn pe Oluwoo tun ti figba kan sọrọ to le da wahala silẹ niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ. Wọn lo sọ ninu ifọrọwerọ kan pe ilu Iwo lo maa n yan ẹni ti yoo jẹ Olubadan.

Wọn ni ija igboro wa ninu ẹjẹ Oluwoo, ko si si eeyan nla nla ti ko ti i ba ja tan, lara wọn ni Ọọni ti Ifẹ, Alaafin ti Ọyọ, Ọrangun ti Ila, Oloye Abiọla Ogundokun, Imrah Adio ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ju gbogbo rẹ lọ, awọn afọbajẹ yii sọ pe o jẹ nnkan ibanujẹ fun awọn pe ẹni to ti ṣẹwọn ri lorileede Amẹrika United States of America (USA) ati Canada ni Oluwoo.

Wọn ni ki Gomina Oyetọla gba ilu Iwo lọwọ idojuti ti Ọba Adewale n mu ba a nipa yiyọ ọ nipo ọba to wa.

 

Leave a Reply