Awọn afurasi mejila to pa ọba alaye l’Agodo foju ba kootu, adajọ ti rọ wọn da sẹwọn

Gbenga Amos, Abẹokuta

 Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, ẹka Zone 2, l’Ọbalende, ti foju awọn afurasi ọdaran mejila tọwọ ba lori ẹsun ṣiṣekupa ọba alaye kan, Alagodo tilu Agodo, Ọba Ọlajide Ayinde Ọdẹtọla han.

Ile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Itori, nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun, lawọn afurasi naa ti kawọ pọnyin rojọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta yii.

Iwe ẹsun ti wọn fi kan wọn, ti nọmba rẹ jẹ MIT/09m/2022 ka pe:

“Ile-ẹjọ yii fẹsun kan iwọ, Abiọdun Sanyaolu, ẹni ọdun marundinlaaadọta, Lukman Azeez, ẹni ọdun mejidinlaaadọta, Fatai Ramon, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Mọnsuru Ramon, ẹni ọdun marundinlogoji, Adeniyi Samuel Akinjiyan, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, Fẹmi Akinsuyi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, Ojo Ọlatidebẹ, ẹni ọdun marundinlogoji, Ṣẹgun Akinjiyan, ẹni ọdun mẹtalelogun, Adewale Ọdunayọ, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Ọladele Idowu, ẹni ọgbọn ọdun, Saheed Ramon, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Ajibọsin Gbeminiyi, ẹni ọdun mẹtalelogoji ati awọn kan ti wọn ti na papa bora, pe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2022, ẹ gbimọ-pọ laarin ara yin, ẹ ṣe akọlu, ẹ si dẹṣẹ apaayan, eyi to lodi si isọri okoolelọọọdunrun (300) iwe ofin ilẹ wa ti ọdun 2002.

“Ile-ẹjọ tun fẹsun kan yin pe ẹ ṣeku pa Ọba Ọlajide Ayinde Ọdẹtọla, Alagodo tilu Agodo, eyi to lodi sofin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun tọdun 2006, ni isọri okoolelọọọdunrun din ookan (319).

Ati pe ẹ tun dana sun oku Ọba Ọlajide Ayinde Ọdẹtọla pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna rẹ ti nọmba rẹ jẹ APP 55 GF, eyi si ta ko isọri ojilenirinwo ati mẹta (443) ofin iwa ọdaran.

Bi wọn ṣe ka ẹsun naa si wọn leti tan, ti wọn lawọn o jẹbi, Adajọ A. F. Adeditan tẹti si alaye olujẹjọ. Lẹyin naa lo sọ wọn satimọle, ọgba ẹwọn ilu Ọba, titi di ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹfa.

Leave a Reply