Awọn agba ijoye Ibadan yi ipinnu wọn pada, wọn lawọn o ṣẹjọ mọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn agbaagba ijoye Ibadan, ti wọn tun jẹ igbimọ Olubadan ilẹ Ibadan, ti gbe ẹjọ ti wọn pe tako Ladọja kuro ni kootu.

Igbesẹ ọhun, eyi to waye ninu ipade ti wọn ṣe laafin Olubadan to wa l’Ọja’ba, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn gbe lati jẹ ko ṣee ṣe fun wọn lati tete fi Olubadan mi-in jẹ lẹyin ipapoda Ọba Saliu Akanmu Adetunji tí í ṣe Olubadan ana.

Lati ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, t’Olubadan ana ti waja lawuyewuye ti bẹrẹ lori ẹni to yẹ ko jọba ati ẹni ti ko yẹ ko jọba nitori ọrọ ọba ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ana, labẹ akoso gomina Abiọla Ajimọbi, fi awọn agba ijoye ilu naa jẹ, eyi to mu ki Osi Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladọja, pe ijọba atawọn ijoye ẹgbẹ ẹ to fi jọba ọhun lẹjọ pe ọba ti wọn jẹ ọhun lodi sofin ati aṣa oye jijẹ ilẹ Ibadan.

Lẹyin ti ile-ẹjọ da Ladọja lare, to si dajọ pe ko lẹtọọ fawọn ijoye ọba kan lati tun jọba ninu ilu kan naa, awọn agba oye wọnyi, ti wọn tun jẹ igbimọ afọbajẹ ilẹ Ibadan, pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun tako idajọ naa. Ẹjọ ọhun to ṣi wa ni kootu dasiko yii lawọn amofin kan n sọ pe o ṣee ṣe ko da ijọba lọwọ kọ lati fi Ọtun Olubadan, Agba-Oye Lekan Balogun, ti ipo ọba kan jọba titi ti idajọ yoo fi waye lori ẹjọ naa ni kootu.

Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣepade pẹlu awọn eeyan yii, to si rọ wọn lati jawọ ninu ọrọ ẹjọ to wa ni kootu, ki wọn si yanju ọrọ naa gẹgẹ bii ọmọ iya laarin ara wọn, ki wọn le fi ẹni to yẹ ko jọba sori itẹ lasiko.

Gbogbo wọn, titi dori Ladọja ti kii ba wọn ṣe pade papọ latigba ti ọrọ yii ti bẹrẹ, ni wọn peju pesẹ sibi ipade ọhún, ti wọn si gba si Gomina Makinde lẹnu ko too di pe wọn gbe igbesẹ lori ọrọ naa nibi ipade wọn ọjọ Tusidee yii.

Nigba to n ba oniroyin sọrọ lẹyin ipade ọhun, Ọtun Balogun ilẹ Ibadan, Agba-Oye Tajudeen Abimbọla, sọ pe “ọjọ kin-ni-ni, oṣu keji, ni wọn sun igbẹjọ yẹn si, ṣugbọn a ti pinnu lati lọọ gbe ẹjọ yẹn kuro ni kootu ṣaaju asiko naa”.

 

Leave a Reply