Awọn agbaagba Onigbagbọ ẹgbẹ APC lawọn yoo darapọ mọ PDP bi Tinubu ba fi Musulumi ṣe igbakeji rẹ

Jọkẹ Amọri
Bi ẹgbẹ oṣelu APC ko ba fẹẹ padanu awọn alatilẹyin wọn kan ti wọn jẹ Onigbagbọ, afi ki wọn yaa mọ ẹni ti wọn yoo fa kalẹ lati ṣe igbakeji oludije funpo aarẹ ẹgbẹ naa, Bọla Hamed Tinubu lasiko idibo ọdun to n bọ. Eyi ko sẹyin bi awọn Onigbagbọ kan ti wọn jẹ oguna gbongbo ninu ẹgbẹ naa ṣe n sọ pe bo ba le jẹ pe ootọ ni ohun ti awọn n gbọ finrin finrin rẹ pe Gomina ipinlẹ Kaduna bayii, El-Rufai, ni wọn maa mu bii igbakeji aarẹ fẹgbẹ APC, a jẹ pe awọn maa fi ẹgbẹ naa silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ alatako, iyẹn PDP niyẹn. Wọn ni awọn ko le fara mọ ọkunrin naa gẹgẹ bii igbakeji aarẹ. Bakan naa ni wọn koro oju si pe ki aarẹ jẹ Musulumi, ki igbakeji rẹ naa tun jẹ Musulumi.
Awọn aṣaaju Onigbagbọ ko fẹ ọkunrin naa gẹgẹ bii igbakeji aarẹ pẹlu ipa to ko lori ọrọ iṣekupani to n ṣẹlẹ sawọn Onigbagbọ ni Guusu Kaduna, nibi ti awọn afẹmiṣofo ti n pa awọn eeyan naa nipakupa, to si jẹ pe ọpọlọpọ wọn jẹ Onigbagbọ.
Awọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa ju lọ awọn agbegbe tọrọ kan si ti naka aleebu si iwa ko kan mi ti gomina naa n hu lori ọrọ yii. Wọn ni pẹlu bi wọn ṣe n ya bo adugbo to jẹ pe awọn Onigbagbọ ni wọn wa nibẹ yii, ti wọn n pa ọmọde, ti wọn n pa agbalagba, ti ọrọ naa ko si yọ ẹnikẹni silẹ, ko ti i si igba kankan ti El-Rufai jade sita pe oun ri ẹnikẹni mu lori iṣẹlẹ naa, tabi ko fi ẹnikẹni jofin.
Ẹni to sọrọ naa fun akọroyin Daily Trust sọ pe pẹlu ipakupa ti wọn n pa awọn eeyan agbegbe Guusu Kaduna, ti ko si ti i dawọ duro di ba a ṣe n sọ yii, inu awọn Onigbagbọ ko dun si gomina Kaduna yii, wọn si ti n sọ pe bo ba fi le jẹ pe oun ni wọn fa kalẹ gẹgẹ bii igbakeji fun Tinubu, a jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn maa darapọ mọ, tawọn si maa dibo fun wọn.
Bakan naa ni wọn koro oju si ki aarẹ jẹ Musulumi, ki igbakeji rẹ naa si jẹ Musulumi, wọn ni igbesẹ naa le ṣakoba fun ẹgbẹ oṣelu APC lasiko idibo ọdun to n bọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: