Jamiu Abayomi
Ọkan ninu awọn ọdaran ti ileeṣẹ ọlọpaa foju wọn han l’Abuja fun ọkan–o–jọkan iwa ọdaran bii idigunjale, ijinigbe, ipaniyan, gbigbe oogun oloro ati bẹẹbẹẹ lọ l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kẹtala oṣu Keje, ọdun yii, yii ni ọmọkunrin kan,
Yusuf Isah, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32) tọwọ ba pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn kọ lu Olori ijọ Omega Fire Ministries Worldwide, Apostle Johnson Suleman. Afurasi naa jẹwọ pe pipa lawọn fẹẹ pa ojiṣẹ Ọlọrun naa ninu ikọlu ọhun to waye l’Oopopona Benin-Auchi, nipinlẹ Edo, ti eeyan mẹfa si ba Iṣẹlẹ ọhun lọ pẹlu ọlọpaa mẹta.
Nigba ti afurasi naa n ba awọn oniroyin sọrọ, o ni, “Ero wa ni lati pa Apostle Suleman, mo n gbọ nigba ti Ilayasu ati Labisca ti a jọ n ṣiṣẹ n sọ laarin ara wọn, ṣugbọn mi o ba wọn da si i, mi o si mọ ẹni to ni ki wọn lọọ pa ọkunrin naa. Niṣe la tọpasẹ rẹ debi ti a ti kọ lu u’’.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa apapọ l’Abuja, Muyiwa Adejọbi, ṣalaye fawọn oniroyin pe, ”Lẹyin iwadii lati ọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni ọwọ ba Isah to jẹ ọmọ Okenne, nipinlẹ Kogi, nibi to fi ṣe ibuba ni Agbaraoluwa Phase 2, ijọka, niluu Akure, nipinlẹ Ondo,ta a si ba ibọn AK47 marun-un, K2 meji ati ọpọlọpọ ọta ibọn to n lọ bii aadọsan(180) ati bọmbu ibilẹ bii mẹrin ninu ile afurasi yii. Lara awọn ibọn ta a ba nile ọkunrin yii jẹ ti awọn ọlọpaa ti wọn pa nibi ikọlu naa”.
O ni afurasi yii jẹwọ pe ọdun 2021 loun darapọ mọ ikọ adigunjale yii, lẹyin ti wọn tu oun silẹ lọgba ẹwọn Olokuta, to ti wa latimọlẹ fun idigunjale lati ọdun 2019. Lẹyin to de lo tun darapọ mọ awọn eeṣin–o–kọku yii lati maa ba iṣe ibi to ti yan laayo yii lọ”.
ALAROYE gbọ pe ikọ yii kundun ki wọn maa digunjalẹ, ki wọn si jiiyan gbe lati gbowo lọwọ awọn ẹbi wọn Wọn ni wọn ti ṣiṣẹ ibi yii bii ọna mẹrin, yato si ti olori ijọ Omega Ministries yii.
O fi kun ọrọ rẹ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa ọdun to kọja ni awọn agbanipa naa dena de ọkọ iranṣẹ Ọlọrunn yii lopopona Benin-Auchi, nipinlẹ Edo, ti eeyan mẹfa si ba Iṣẹlẹ ọhun lọ pẹlu ọlọpaa mẹta.