Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Oludije funpo aṣoju-ṣofin fun ẹkun idibo apapọ Ifẹdapọ, n’ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ṣaki, ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki ati Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, labẹ ẹgbẹ oṣelu Accord, Ọnarebu Jacob Funmi Ogunmọla, lawọn agbanipa kọ lu ile rẹ to wa loju ọna lrawọ, niluu Agọ-Arẹ, nijọba ibilẹ Atisbo, ṣugbọn ti ori ko o yọ, tori wọn ko ba a nile.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn agbanipa naa ya wọ ile rẹ ni deede aago kan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun, lọganjọ oru Ọjọọru, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kọkanla yii, nibi tawọn mẹrin ti wọn da aṣọ dudu boju ninu ọkọ Hilux dudu kan ti wọn gbe wa, ti bẹrẹ si i gba geeti abawọle oludije naa.
Awọn agbanipa naa ni ki baba ọlọdẹ to n ṣọ ile ọhun ṣilẹkun fawọn lẹrọ. Lẹyin to ṣilẹkun tan, ibọn la gbọ pe wọn gbe seti baba ọhun, pe ko tete maa mu awọn lọ sibi ti ọga rẹ wa wọọrọwọ, abi kawọn fibọn tu agbari ẹ ka.
Lẹyin ti wọn yẹ gbogbo ile naa wo finni-finni ti wọn ko ri ẹni ti wọn wa wa, ni wọn ba tilẹkun abawọle mọ ọlọdẹ naa ko ma baa pariwo sita pe awọn kan ti wa lati wa gbẹmi ọga oun.
Ọmọ ẹgbẹ Accord kan, Oloye Tijani Mayor Balogun, ṣapejuwe iṣẹlẹ yii bii apẹẹrẹ buburu tawọn araalu yoo maa reti ko too di pe asiko ti ibo yoo waye.
Tijani waa rọ ijọba Muhammadu Buhari lati pese aabo to mọyan lori fawọn araalu, paapaa fawọn oloṣelu ṣaaju asiko idibo.
ALAROYE ṣapa lati ba oludije naa sọrọ, ṣugbọn ko ṣee ṣe tori titi dasiko ta a fi n ko iroyin jọ, ko gbe aago rẹ, ko si ti i fesi si atẹjiṣẹ ta a fi sọwọ si i, bẹẹ ni ko si larọọwọto rara.
Awọn araalu kan ti n naka ifura si awọn ẹgbẹ oṣelu alatako mi-in ti wọn ro pe oludije naa yoo jẹ idiwọ fun wọn lati jawe olubori.