Ọlawale Ajao, Ibadan
Ori lo ko abẹ́ṣẹ́-kù-bíi-òjò nni, Ridwan Oyekọla, ọdọmọde to n ṣoju orileede yii ninu idije ere ẹ̀ṣẹ́ kikan yọ lọwọ iku ojiji nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn afẹ̀míṣòfò da oun atawọn ọrẹ ẹ̀ lọna, ti wọn sì rọjo ibọn le wọn lori.
Ridwan, ẹni tàwọn èèyàn tun mọ sí Scorpion ni bàǹtẹ́ WBF fawọn ọdọmọde abẹ̀ṣẹ́-kù-bíi-òjò lagbaaye wa lọwọ ẹ̀ bayii lẹyin to fagba hàn ọmọ orileede Argentina, Lukas Matias Montesino, ninu ija to já gbẹyin laipẹ yii.
Oun atawọn ọrẹ ẹ̀ meji la gbọ pe wọn wà nínú ọkọ ayọkẹlẹ Toyota rẹ lasiko ti awọn ẹruuku meji ọhún gbìdánwò lati ran wọn lọ sọrun apapandodo.
Iṣẹlẹ ọhun waye lẹyìn ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi ẹbun sọ̀wédowó mílíọ̀nù mẹwàá naira ta ògbóǹtarìgì elere ẹ̀ṣẹ́ kíkàn yii lọrẹ gẹgẹ bíi ọmọ ìlú Ìbàdàn, nipinlẹ Ọyọ, to n gbe ogo orileede Naijiria ga fún bo ṣe fẹyin aṣoju orileede Argentina balẹ ninu idije ẹṣẹ kikan agbaye to waye laipẹ yii.
Nigba to n fìdí iroyin yii múlẹ̀ fakọroyin wa, Scorpion ṣalaye pe, ‘Lati ọna Agodi Géètì ni mo ti n bọ, mo n gbe ọrẹ mi tó sìn mi lọ síbi tí mo ti gba ṣẹ́ẹ̀kì ti Gomina Ṣeyi Makinde fún mi lọ sí Mọkọla lawọn ẹni yẹn da wa lọna pẹlu ibọn.
“Lati NTA la ti ṣakiyesi pe moto kan n tẹ̀lé wa lẹyin. Bá a ṣe dé Total Garden ni wọn yọ ibọn sí wa.
Nṣe la sáré yiwọ sí ẹgbẹ kọ́tà. Gbogbo taya ọkọ wa ni wọn fibọn fọ. Awọn ọrẹ mi mejeeji fara pa diẹ ṣugbọn a dupẹ pe Ọlọrun kó wa yọ.”
Awọn to wa ninu mọto pẹlu Scorpion ni Adeṣina Sherif ati Habeeb Igẹ̀ ti oun naa jẹ ọga láàrin àwọn ọ̀dọ́ to n jẹṣẹ lorileede yii.
Ẹni tó jẹ onígbọwọ́ Ridwan Oyekọla, Ọgbẹni Ṣọla Ayọdele, ti waa gba ijọba niyanju lati pèsè eto aabo tó péye fún Scorpion,