Awọn agbebọn da awọn arinrin-ajo lọna Ẹrin Ijẹṣa, ni wọn ba ko lara wọn lọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Bashir Adewinbi, ti sọ pe titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to le sọ ni pato iye awọn arinrin-ajo tawọn agbegbọn ji gbe loju ọna Omoh si Ẹrin-Ijeṣa nijọba ibilẹ Oriade nipinlẹ Ọṣun.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, la gbọ pe awọn agbegbọn naa ya soju titi, ti wọn si da awọn arinrin-ajo naa duro, lẹyin iṣẹju diẹ ni wọn ko diẹ lara wọn lọ sinu igbo to wa lagbegbe Ori Oke Omoh, ti wọn si fi awọn to ku silẹ.

Nigba ti Adewinbi n fidi eyi mulẹ, o ni bi awọn ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn ẹsọ Amọtẹkun ti fọn sinu igbo naa lati le tu awọn arinrinajo yii silẹ, ati lati le ri awọn ọdaran naa mu.

Ninu ọrọ tirẹ, Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe eeyan meji pere lawọn agbegbọn naa ji gbe lara awọn arinrinajo ọhun, ti wọn si fi awọn to ku silẹ.

Ọpalọla sọ pe obitibiti awọn ọlọpaa ni wọn ti wa nibẹ bayii, idaniloju si wa pe ọwọ yoo tẹ awọn agbegbọn ọhun laipẹ.

Ẹnikan to n gbe ninu ilu naa to ba ALAROYE    sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣalaye pe agbegbe naa ti fẹẹ di ẹrujẹjẹ lọwọ awọn agbebọn.

O ni ki i ṣe igba akọkọ tiru iṣẹlẹ naa yoo ṣẹlẹ nibẹ niyi, ati pe wọn ti yinbọn fun awọn Amọtẹkun lorita yẹn gan-an ri. O ni ọlọpaa atawọn Amọtẹkun ti wa ninu igbo naa bayii.

Leave a Reply