Awọn agbebọn dana sun eeyan mẹwaa, wọn dumbu awọn kan, wọn si ko obinrin meje wọgbo lọ ni Niger

Adefunkẹ Adebiyi

Ipayinkeke ko ti i kuro nilẹ lawọn agbegbe bii Kachiwe ati Shape, nipinlẹ Niger, nitori laarin ọsẹ lawọn oniṣẹ ibi ya wọ ibẹ. Wọn dana sun eeyan mẹwaa, wọn dumbu awọn mi-in bii ẹran, wọn dana sun ile bo ṣe wu wọn, wọn si ko awọn iyawo oniyawo meje wọgbo lọ.

Agbegbe Sarkin Pawa, nijọba ibilẹ Munya, ipinlẹ Niger, niibi ti wọn n pe ni Kachiwe yii wa. Akọwe ijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni James Jagaba, ṣalaye iṣẹlẹ buruku ti ko ti i tan nilẹ naa pe, ”Awọn janduku naa dana sun gbogbo ile ni, wọn jo eeyan mẹwaa nina lojukoroju, wọn ko awọn obinrin olobinrin mẹwaa lọ. Nigba ti wọn ṣe iyẹn tan ti wọn n lọ, wọn pade awọn eeyan meji kan lọna, mọto awọn iyẹn bajẹ ni. Wọn da wọn duro, wọn si pa wọn soju ọna nibẹ. Nibi ti wọn ti n ṣe iyẹn lọwọ ni mẹta ninu awọn obinrin mẹwaa ti wọn n ko lọ ti raaye sa mọ wọn lọwọ, bi wọn ṣẹ ko awọn meje yooku wọgbo lọ niyẹn.

“Gbogbo ilu ni wọn fọwọ ba, ti wọn sọ di ahoro. Awọn obinrin mẹta to sa mọ wọn lọwọ yẹn lo jẹ ka mọ ohun to ṣẹlẹ. Awọn naa ko gbadun, ara wọn n gbọn ni, niṣoju wọn ni wọn ṣe dana sun awọn eeyan mẹwaa, niṣoju wọn ni wọn ṣe dumbu awọn mi-in, ohun ti wọn ri yẹn ko jẹ kawọn naa wa ni alaafia ara titi dasiko yii.”

Ọkunrin yii tẹsiwaju pe awọn apaayan naa tun lọ si Abule Shape, wọn dumbu eeyan mẹsan-an nibẹ, awọn ti wọn raaye sa lọ nibẹ, ẹni ori yọ o dile ni wọn fi dọgbọn sa lọ. O ni lẹyin ti wọn kuro nibẹ ni wọn tun lọ sibi kan ti wọn n pe ni Gogope, nipinlẹ Niger kan naa, wọn si tun paayan meje.

Lori bi wọn ṣe ri gbogbo iṣẹ buruku yii ṣe lai jẹ pe ẹnikẹni da wọn lọwọ kọ, wọn ni ẹrọ ibara ẹni sọrọ ti ko ṣiṣẹ lawọn ilu naa lo fa a, nitori ko si bawọn eeyan ṣe fẹẹ pe ibomi-in pe aburu n ṣẹlẹ lọwọ lapa ọdọ awọn.

Ki wọn too gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni Kansu ilu paapaa, ilẹ ti ṣu gbere, nnkan si ti bajẹ kọja sisọ.

 

Leave a Reply