Awọn agbebọn ji gbajumọ onisowo kan gbe n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu Ilọrin,

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lawọn agbebọn to dihamọra pẹlu ibọn ji gbajugbaja oniṣowo kan, Arabinrin Asiat Ishao, gbe lọ ni agbegbe Okoolowo, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (South) nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii alẹ ti arabinrin naa fẹẹ kuro lọọfiisi rẹ to wa ni adojukọ Bioraj Pharmacy, Okoolowo Ilọrin, ni awọn ajinigbe naa yọ si i, wọn n yinbọn soke lera lera titi ti wọn fi le obinrin naa jade ninu mọto rẹ, ti wọn si ji i gbe sa lọ.

Sikin tutu ati ẹja ni wọn sọ pe Asiat n ta ni ọfiisi rẹ. Titi di igba ta a fi pari akojọ iroyin yii, wọn o ti i gburoo awọn agbebọn naa. Bẹẹ ni wọn ko ti i pe mọlẹbi obinrin yii lati sọ iye ti wọn fẹẹ gba.

Ṣugbọn awọn mọlẹbi ni awọn ti fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, wọn si ti fi awọn lọkan balẹ pe awọn yoo doola ẹmi arabinrin naa.

Leave a Reply