Awọn agbebọn ji agunbanirọ atawọn mẹjọ mi-in gbe ni Zamfara

Faith Adebọla

Ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Jennifer Iorliam Awashima, agunbanirọ to ṣẹṣẹ n lọ sibi ti wọn yan an si lati ṣiṣẹ sinlu rẹ, ti dero inu igbo, awọn janduku agbebọn ni wọn ji i gbe loju ọna l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣalaye pe akẹkọọ to ṣẹṣẹ gboyejade ninu imọ ede Gẹẹsi lati Fasiti ipinlẹ Benue wa lara awọn ti wọn yan lati ṣiṣẹ sinlu rẹ nipinlẹ Kebbi, ibẹ naa lo n rin irinajo lọ tawọn janduku agbebọn fi ṣakọlu si bọọsi elero mejidinlogun to wọ lagbegbe kan nijọba ibilẹ Tsafe, nipinlẹ Zamfara, ti wọn si ji i gbe.

Ẹgbọn ọmọbinrin naa, Arabinrin Awashima, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe “Awọn agbebọn kan ti ṣakọlu si mọto ero to n lọ si ipinlẹ Kebbi, ero mẹsan-an lo wa ninu mọto naa, gbogbo wọn ni wọn ji gbe, aburo mi si wa ninu wọn, wọn laṣọ ṣọja lawọn agbebọn naa wọ.

‘‘Wọn lawakọ naa ro pe awọn ṣọja ti wọn n ṣiṣẹ aabo lagbegbe naa lo da awọn duro ni, eyi lo fi duro nigba ti wọn da a duro, ṣugbọn niṣe lawọn janduku to ku rọ jade lati inu igbo lẹgbẹẹ ibi ti wọn duro si, ni wọn ba ji wọn gbe.

‘‘Latigba ti aburo mi ti wọ ọkọ ni mo ti n pe nọmba ẹ, o kọkọ ba mi sọrọ, ṣugbọn nigba to ya, ko sẹni to gbe ipe rẹ mọ. Ẹru bẹrẹ si i ba mi, lọjọ keji ni ọkunrin kan gbe ipe naa, o loun ni dẹrẹba to wa ọkọ naa, ati pe awọn agbebọn ti ṣakọlu sawọn, wọn si ti ji gbogbo ero inu ọkọ naa gbe, o ni nnkan bii aago mẹfa aṣaalẹ niṣẹlẹ naa waye.

‘‘A ti lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa, awọn ọtẹlẹmuyẹ ati ẹka ileeṣẹ awọn agunbanirọ, awọn agbebọn naa ko ti i sọ iye tawọn maa gba rara.”

Wọn ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Zamfara ko ti i fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, tori ko gbe ipe rẹ.

Leave a Reply