Awọn agbebọn ji alaga kansu tẹlẹ atawọn mẹrin mi-in gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn kan ti wọn ko ti i mọ ti ji alaga ijọba ibilẹ Ilejemeje tẹlẹ, Ọmọọba Bamigboye Adegoroye, atawọn mẹrin mi-in gbe.

Adegoroye to tun jẹ ọga ati oludari pataki kan ninu ẹgbẹ SWAGA, to n ṣe ipolongo idibo aarẹ fun  gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu ni wọn ji gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ l’Ado-Ekiti, alaga ijọba ibilẹ Ifẹsowapọ, Ọgbẹni Kayọde Akerele, sọ pe Adegoroye ati ẹnikan to wa ninu ọkọ rẹ ni wọn ji gbe ni ọna Iṣan si Iludun-Ekiti, nirọlẹ  ọjọ Aje, Mọnde.

O ṣalaye pe ni deede aago meje aabọ alẹ ni wọn ko wọn wọ inu igbo kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ. O sọ pe niṣe ni wọn da ibọn bo ara ọkọ ti alaga ijọba ibilẹ tẹlẹ yii wa lo jẹ ko duro lojiji.

Bakan naa ninu ijinigbe miiran, Alaga ijọba ibilẹ Ẹrọ, Ọgbẹni Akin Alebioṣu, sọ pe awọn mẹta miiran ti wọn jẹ oniṣowo eedu ni wọn tun ji gbe n’Ikun-Ekiti, ni bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ yii kan naa.

Alebioṣun sọ pe lasiko ti adari awọn oniṣowo eedu naa toruko rẹ n jẹ Olu, to jẹ ọmọ bibi ilu Ikun-Ekiti lọ si eti odo Ẹrọ ni wọn ji wọn gbe.

Wọn ti waa rawọ ẹbẹ si Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Tunde Mobayọ, lati mura si eto aabo, pataki ju lọ ni ọna Ayede-Isan-Iludun to ti n da bii ojuko fun awọn ajinigbe.

Nigba to sọrọ lori ọrọ naa, ọga awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Joe Kọmọlafẹ, sọ pe awọn ẹṣọ oun ti n ṣe ohun gbogbo lati darapọ mọ awọn agbofinro miiran ki wọn le ṣe awari awọn ti wọn ji gbe naa.

 

O ni o jẹ ohun ibanujẹ pe gbogbo ọna ijọba ibilẹ Mọba, Ilejemeje ati Ọyẹ to jade si ipinlẹ Kogi lo ti di ẹrujẹjẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lasiko yii.

O ṣeleri pe awọn ọmọ ogun oun ti bẹrẹ igbesẹ lati gba awọn ti wọn ji gbe naa silẹ lai fara pa.

Leave a Reply