Awọn agbebọn ji Baalẹ Apanpa atiyawo rẹ gbe lọ labule kan n’Ibadan

Titi di ba  a ṣe n sọ yii ni awọn ara abule ṣi n wa Baale Ararọmi, Alaaji Tafa Apanpa, atiyawo rẹ ti awọn agbebọn ji lọ ni oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni abule kan to wa ni agbegbe Bakatari, nijọba ibilẹ Ido, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), to gbọ nipa iṣẹlẹ naa ṣe sọ, lasiko arọọda ojo to waye lalẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn ẹni ibi naa ya wọ abule to wa laarin aala ipinlẹ Ọyọ ati Ogun yii, ti wọn si ji baalẹ naa ati iyawo rẹ lọ.

Titi di asiko ta a n kọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ ibi ti awọn eeyan naa wa, bẹẹ ni awọn ajinigbe naa ko ti kan si mọlẹbi wọn lati beere ohunkohun.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Osifẹsọ, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti n gbe igbesẹ lati ṣawari baalẹ naa ati iyawo rẹ.

Leave a Reply