Awọn agbebọn ji baba ati ọmọ gbe lọ ni Ọ̀sẹ́

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọkunrin kan to jẹ akẹkọọ ileewe girama awọn ọmọ ogun oju ofurufu to wa ni Ìmèri, nijọba ibilẹ Ọsẹ, Jethro Onose, ati baba rẹ, Maliki Onose, lawọn agbebọn kan ti ji gbe sa lọ lasiko ti ọmọ naa n pada sileewe rẹ laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe ipinlẹ Edo ni Jethro ati baba rẹ ti n bọ lati pada si ileewe to ti n kẹkọọ lẹyin ọlude ọlọsẹ mẹta ti wọn gba, ki awọn mejeeji too bọ sọwọ awọn agbebọn to ji wọn gbe wọnu igbo lọ laarin oju ọna marosẹ Edo si ipinlẹ Ondo.

Awọn ti wọn ji gbe ọhun la gbọ pe wọn ti fọgbọn ba awọn ẹṣọ alaabo sọrọ laṣiiri lori aago lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, ati lati jẹ ki wọn mọ agbegbe ibi ti wọn ko wọn pamọ si lasiko naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ri awọn mejeeji ti wọn ji gbe naa gba pada lai fara pa.

 

Leave a Reply