Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Titi di bi a ṣe n ko iroyin yii jọ lawọn ẹṣọ alaabo ipinlẹ Kwara, ṣi n lakaka lati doola ẹmi oloye ijọ kan, Deakoni Fẹmi Ajayi ati baba rẹ, tawọn agbebọn ji gbe niluu Ìsánlú-Ìsin, nijọba ibilẹ Ìsin, nipinlẹ Kwara, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ Kẹtala, oṣu Keje yii.
ALAROYE gbọ pe ṣe ni awọn agbebọn naa ya bo ilu Ìsánlú-Ìsin, ni nnkan bii aago meje alẹ, ti wọn si yinbọn soke leralera, eyi to mu ki ibẹru-bojo gbọkan gbogbo araalu, ti ko si sẹni to le jade lasiko ta n wi yii.
Ile Deakoni Fẹmi Ajayi, to wa ni First Baptist Grammar School, ilu Ìsánlú-Ìsin, ni wọn gba lọ, wọn ba ọkọ wọn jẹ, wọn si ji oun ati baba rẹ gbe sa lọ.
Awọn adari agbegbe naa ti waa rọ awọn eeyan ki wọn tete mura si adura o, tori pe ohun ta o ba fẹ ko bajẹ, oju la a mu to o, . Bakan naa ni wọn ke si awọn ẹṣọ alaabo ki wọn dide si iṣẹlẹ naa kia lati doola awọn eeyan yii kuro lakata awọn ajinigbe ọhun.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni Kọmiṣanna ọlọpaa, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, ti ko awọn ẹṣọ alaabo, ọlọpaa, pẹlu ajọṣepọ fijilante, lọ si agbegbe naa, to si ni ki wọn fọ gbogbo inu igbo ọhun yẹbẹ-yẹbẹ lati doola ẹmi mọlẹbi meji to wa lakata awọn agbebọn ọhun.
O ṣeleri pe awọn yoo si fi awọn ajinigbe naa jofin tọwọ ba tẹ wọn.
Titi di asiko ta a n ko iroyin yii jọ, awọn ajinigbe naa ko ti i pe mọlẹbi awọn eeyan yii lati beere fun owo kankan.