Awọn agbebọn ji Babs oniburẹdi gbe n’Ifẹwara, miliọnu marun-un ni wọn n beere

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin oniburẹdi kan to n gbe niluu Ifẹwara, nipinlẹ Ọṣun, Sikiru Adebisi, la gbọ pe awọn agbebọn ti ji gbe bayii lagbegbe Oke-Ado, niluu naa. Miliọnu marun-un Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ, wọn si sọ pe bi awọn mọlẹbi rẹ ko ba tete wa owo naa, ṣe lawọn yoo pa a.

Ẹnikan to n gbe niluu naa, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri, sọ fun ALAROYE pe nidaaji ọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ni wọn ji Adebisi gbe, ni nnkan bii aago mẹrin idaji to fẹẹ lọọ gbe burẹdi fawọn onibaara rẹ pẹlu bọọsi Sienna to fi n taja. N lawọn agbebọn naa ba da a lọna, ti wọn si ji i gbe lorita Oke-Ado.

A gbọ pe awọn mọlẹbi rẹ ti kọkọ lọọ fọrọ naa to awọn   agbofinro leti nigba ti wọn ko tete ri i ko pada wale lọjọ Sannde.

Ṣugbọn nigba ti awọn agbebọn naa pe wọn lori foonu, ti wọn si beere miliọnu marun-un Naira ni wọn too mọ pe o ti ko sọwọ.

Latigba naa lawọn mọlẹbi rẹ ti n wa owo ọhun kaakiri, ṣugbọn a gbọ pe awọn agbebọn ọhun ti din owo naa ku si ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ẹṣọ alaabo bii ọlọpaa, ọlọdẹ atawọn figilante ti wa ninu igbo lati ṣawari ọkunrin naa.

 

Leave a Reply