Awọn agbebọn ji dẹrẹba ati ero mẹrin gbe loju ọna Ayetoro s’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awakọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Kamọrudeen Ọlatẹju, ti di awati bayii, bẹẹ si ni awọn mẹrin ninu ero ọkọ to n wa loju ọna to lọ si Abẹokuta lati Ayetoro naa. Awọn agbebọn kan ni wọn ya bo wọn ni nnkan bii aago marun-un ku iṣẹju marun-un idaji ọjọ Satide, ogunjọ, oṣu keji yii.

Bo tilẹ jẹ pe eeyan mẹrin lawọn ẹbi ti eeyan wọn di awati sọ pe awọn n wa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe eeyan meji ni wọn ji gbe, o si ni ọwọ ti ba ẹni kan ninu awọn ajinigbe naa.

Obinrin kan ti wọn tun darukọ ẹ pe o wa ninu awọn ti wọn ji gbe ni Saidat Adediran. ALAROYE gbọ pe teṣan ọlọpaa Imala ni awọn ẹbi awọn eeyan naa mu ẹjọ lọ. Ọgbẹni Abubakar Ọlatẹju ati Kẹhinde Adediran lo lọọ fi to wọn leti nibẹ pe awọn kan ji awọn eeyan awọn gbe, awọn ko si ti i ri wọn.

Titi ta a fi pari iroyin yii, wọn ko ti i ri awakọ ti inagijẹ n jẹ Charger naa, bẹẹ ni wọn ko ti i ri awọn mẹta yooku pẹlu.

Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja lọhun-un lawọn kan da iya kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ajọkẹ Iṣọla duro lori ọkada to wa, lagbegbe Igbo-Ori, ni Yewa, ti wọn gbe e wọgbo lọ.

Ọjọ keji lẹyin ti wọn gbe e lọ naa ni wọn ri oku ẹ ninu igbo ti wọn pa a si.  Ọkọ ọmọ iya yii lo n gbe e lọ lori ọkada ti wọn fi ko wọn lọna, ọkunrin naa si sọ pe Fulani lawọn eeyan to ko awọn lọna ti wọn fipa da awọn duro ọhun.

O ni wọn yinbọn soun, ibọn naa ko ran oun, oun si pada rọna sa lọ mọ wọn lọwọ, ṣugbọn niṣe ni wọn gbe iya iyawo oun wọgbo lọ, ko too di pe awọn pada ri oku iya naa ninu igbo.

Leave a Reply