Awọn agbebọn ji eeyan mẹta gbe niluu Oṣu, ni wọn ba n beere miliọnu lọna aadọta naira

Florence Babaṣọla

 

Awọn arinrinajo mẹta la gbọ pe awọn agbebọn ji gbe lopin ọsẹ to kọja niluu Oṣu loju-ọna Ifẹ si Ileṣa.

Ọkan lara awọn arinrinajo naa ti orukọ rẹ n jẹ Usman ni wọn pe ni aburo Seriki Hausa ti ilu Iyere, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Atakumọsa, niluu Ileṣa, nigba ti wọn ko ti i mọ awọn meji to ku.

A gbọ pe inu igbo kijikiji kan niluu Oṣu ni wọn ko wọn lọ ni kete ti wọn da mọto ti wọn wọ duro, gbogbo igbiyanju awọn ọlọdẹ lati ri wọn gba silẹ ni ko si ti i so eso rere kankan.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Seriki Fulani Iyere, Haruna Tanko, sọ pe loootọ ni wọn ji aburo oun atawọn meji mi-in gbe. O ni ẹnikan lara awọn ajinigbe naa ti pe oun lori foonu, wọn si n beere fun miliọnu lọna aadọta naira (#50m).

O ni awọn ko ti i ri owo naa ko jọ, bẹẹ ni awọn ajinigbe ko ti i tu aburo oun atawọn yooku silẹ, ṣugbọn awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ lori ọrọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe wọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn leti lọjọ Ẹti to kọja, bẹẹ ni awọn n ṣiṣẹ lọwọ lati gba awọn arinrinajo naa silẹ, ki ọwọ si tẹ awọn ajinigbe naa.

 

Leave a Reply