Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ninu oko rẹ to wa ni agbegbe Oke-Jia, Egbejila, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lawọn agbebọn ti ji igbakeji ọga agba ajọ aṣọbode tẹlẹ nilẹ yii, Mohammed Zarma.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to lọ yii, lo ti sọ pe awọn ajinigbe ya bo agbegbe Egbejila, ti wọn si n sọ oniruruu ede lẹnu, wọn si ji igbakeji ọga asọbode tẹlẹ lorileede yii lọ ninu oko rẹ to wa lagbegbe Oke-Jia, Egbejila, niluu Ilọrin.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti n sa gbogbo ipa rẹ lati doola ẹmi ọkunrin ọhun. Labẹ idari Kọmisanna ọlọpaa, Tuesday Assayomo, ni wọn ti ko awọn ẹṣọ alaabo si gbogbo agbegbe naa ki wọn le doola ẹmi ẹni ti wọn ji gbe laaye, ki wọn si mu awọn ajinigbe ọhun lati fi wọn jofin.
Kọmisanna ọlọpaa ti waa fi ẹmi awọn mọlẹbi Mohammed lọkan balẹ pe ki wọn ma ba ọkan jẹ rara, ileeṣẹ ọlọpaa yoo doola ẹmi ọmọ wọn kuro lakata awọn ajinigbe, ti yoo si darapọ mọ wọn laipẹ.