Awọn agbebọn ji iya olori awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ Kogi lọ

Faith Adebọla

Abilekọ Seriya Raji, iya to bi Olori awọn oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Kogi, Ọgbẹni AbdulKarim Jamiu Asuku, ti dero ahamọ awọn ajinigbe, wọn lawọn agbebọn ni wọn ji mama arugbo naa gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

AbudulKarim ni olori awọn oṣiṣẹ ọba lọfiisi gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello.

Ba a ṣe gbọ, inu ile mama naa to wa ni Inese/Ovakere, laduugbo Nagazi, nijọba ibilẹ Adavi, lawọn agbebọn kan ti ya bo o ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ko pe tobinrin naa kirun alẹ tan ni wọn de’bẹ, wọn ko mama naa ni papamọra, wọn si ji i gbe wọ’gbo lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, DSP Williams Onye Aya ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn agbofinro ti bẹ sode, wọn si ti n tọpasẹ awọn ajinigbe naa, ati pe ireti wa pawọn yoo le doola ẹmi mama agbalagba ọhun.

O lawọn ajinigbe naa ko ti i kan si mọlẹbi Abilekọ Raji, wọn o si ti i sọ iye ti wọn maa gba lati tu u silẹ, titi di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply