Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Titi di bi a ṣe n sọ yii jọ lawọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Kwara, si n lakaka lati doola ẹmi iyawo ati ọmọ meji, to jẹ ti arakunrin kan to sẹsẹ tilu oyinbo de, Alaaji Sikiru, tawọn agbebọn ji gbe niluu Ọ̀kànlé-Fajérọ̀mí, nijọba Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara, loru ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa yii. Lasiko ti wọn n sun lọwọ ni wọn lọọ ji wọn gbe.
ALAROYE gbọ pe ṣe ni awọn agbebọn naa ya bo abule Ọ̀kànlé-Fajérọ̀mí, ti wọn si yinbọn soke leralera, eyi to ji gbogbo awọn to n sun lọwọ silẹ, ti ibẹru bojo si gbilẹ lọkan gbogbo araalu, ti ko si sẹni to le jade sita lọjọ naa. Ile arakunrin to sẹsẹ tilu oyinbo de ọhun, Alaaji Sikiru, ni wọn gba lọ, wọn ja ilẹkun mọ wọn lori, wọn si ji iyawo ati ọmọ rẹ meji gbe sa lọ.
Baalẹ ilu Ọ̀kànlé-Fajérọ̀mí, Olugbese tilu Ọ̀kànlé, Alaaji Abdulfatai Ọlasunkanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni loruganjọ, nigba ti awọn n sun lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ni awọn agbebọn naa ya wọlu, ti wọn si ji mọlẹbi Alaaji mẹta gbe lọ. O tẹsiwaju pe pẹlu igbiyanju awọn fijilante, wọn ti ri ẹni kan doola ninu awọn mẹta ti wọn jigbe ọhun, sugbọn awọn agbebọn naa yinbọn mọ fijilante kan lẹsẹ.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ o ni awọn ẹṣọ alaabo, ọlọpaa, pẹlu ajọsepọ fijilante, ti wa ninu igbo lati doola ẹmi mọlẹbi meji to wa lakata awọn agbebọn ọhun.