Awọn agbebọn ji olori abule kan gbe, wọn ni kaadi ipe, tiramadọọlu, siga ati epo bẹtiroolu lawọn fẹ

Monisọla Saka

Awọn Agbebọn ti ji Ọgbẹni Ayuba Dodo Dakolo to jẹ Baalẹ abule Rajina to wa nijọba ibilẹ Kachia, n’ipinlẹ Kaduna, gbe.
Baba yii ni wọn ji gbe pẹlu awọn agbẹ mi-in ni agbegbe Kurmi, nitosi Chikwale, nijọba ibilẹ kan naa.
Abule Rijana to jẹ ilu kan to wa loju ọna marosẹ Kaduna si Abuja, ni awọn ajinigbe yii ti n yọ lẹnu fun igba pipẹ, niṣe lawọn olubi ẹda yii maa n dana lati ji awọn arinrin-ajo gbe.
Amọ ṣa o, l’Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn ajinigbe yii kan si awọn olori ilu naa pẹlu iwe meji ti wọn kọ, awọn ohun ti wọn fẹ ki wọn too le da awọn eniyan wọn silẹ. Lara awọn nnkan ti wọn lawọn n fẹ ni: ọpọlọpọ galọọnu epo bẹtiroolu, ọili ẹnjinni, oogun oloro Tiramadọọ (Tramadol) ati ọpọlọpọ siga.
Ọkan ninu awọn eniyan ilu ọhun tun sọ pe, “A ti ba baba baalẹ sọrọ, alaafia ni wọn wa. Ṣugbọn awọn araabi ti ni ka fun awọn ni kaadi ipe, pe awọn yoo pa wọn ta a ko ba fi kaadi ranṣẹ”.

Leave a Reply