Awọn agbebọn ji oludamọran pataki si gomina gbe o

Faith Adebọla

Oludamọran pataki si Gomina ipinlẹ Zamfara lori ọrọ oṣelu, Alaaji Ibrahim Ma’aji, ti dero ahamọ awọn ajinigbe bayii. Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta yii, lawọn afurasi agbebọn kan ya bo ọkunrin naa ninu ile rẹ to wa lagbegbe Mareri, niluu Gussau, olu-ilu ipinlẹ Zamfara.

Ẹnikan to sun mọ awọn mọlẹbi oludamọran pataki ọhun, Ọgbẹni Mohammed Ahmed, ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe titi di ba a ṣe n sọ yii, awọn ajinigbe naa ko ti i kan sawọn mọlẹbi lori aago nipa nnkan ti wọn maa gba ti wọn yoo fi tu onde wọn silẹ.

“Wọn o ti i pe ẹnikẹni lori aago, ṣugbọn a n reti ki wọn pe, tori gbogbo wa niṣẹlẹ naa ba labo. A ti n pe nọmba aago rẹ, o si n lọ, aago rẹ n dun, amọ ko sẹni to gbe e.”

Bakan naa ni ọmọ Oludamọran pataki yii, Lukman Ibrahim, ṣalaye pe ẹyinkule ni awọn ajinigbe naa gba wọle, wọn dihamọra, wọn si gbe ibọn lọwọ, gbogbo wọn ni wọn daṣọ dudu boju. O ni bi wọn ṣe wọle, inu yara oun ni wọn wa, oun wa lori bẹẹdi, ni wọn ba paṣẹ foun pe koun mu wọn lọ sibi ti dadi oun wa, oun si ṣe bẹẹ, tori wọn kọju ibọn soun ni.

Lukman ni awọn ti fọrọ yii to ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara leti, gomina ipinlẹ naa, Bello Matawalle, si ti gbọ nipa ẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko le sọ pato nipa igbesẹ ti wọn n gbe lori ọrọ yii.

Tẹ o ba gbagbe, ipinlẹ Zamfara wa lara awọn ipinlẹ agbegbe Oke-Ọya tawọn ajinigbe atawọn agbebọn ti n han awọn araalu leemọ, bi wọn ṣe n ṣakọlu si wọn, bẹẹ ni wọn n ji wọn gbe gbowo, iṣẹlẹ naa si ti n waye leralera lẹyin eto idibo to waye lọsẹ to lọ.

Leave a Reply