Awọn agbebọn ji olujọsin mẹẹẹdọgbọn gbe lasiko ti isin n lọ lọwọ

Adewumi Adegoke

Olujọsin bii mẹẹẹdọgbọn ni awọn agbebọn ti ji gbe lọ bayii ni ṣọọṣi kan ti wọn pe ni New Life for All Church, to wa ni Dantsauni, ni adugbo kan ti wọn n pe ni Gidan Haruna, nijọba ibilẹ Kankara, nipinlẹ Katsina.

Lasiko ti wọn n ṣe isin lọwọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn agbebọn to le ni ọgọrun-un naa ya wọ ileejọsin ọhun, ti wọn si ji awọn to waa jọsin fun Ọlọrun lọ ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Oludamọran agba fun gomina ipinlẹ Katsina lori ọrọ to jẹ mọ ẹsin awọn Onigbagbọ, Rẹfurẹndi Ishaya Jurau, ṣalaye pe loootọ ni awọn agbebọn wọ ṣọọṣi ọhun ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ lasiko ti awọn eeyan naa n ṣe ijọsin lọwọ, ti wọn si ji bii mẹẹẹdọgbọn ninu awọn olujọsin ko lọ. Bẹẹ lo ni wọn ṣe olori ijọ naa, Pasitọ Haruna, leṣe.

O fi kun un pe awọn agbofinro atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe wọn gba awọn ti wọn ji gbe lọ naa silẹ lai fara pa.

Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Gambo, sọ pe eeyan marun-un pere ni awọn agbebọn ọhun ji, ki i ṣe mẹẹẹdọgbọn rara. O ni loootọ ni awọn agbebọn naa ya wọ ṣọọṣi New Life for All Church, lasiko ti wọn n ṣe isin lọwọ ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ti wọn si da ibọn bolẹ ni kikankikan lati fi dẹruba awọn olujọsin naa ko too di pe wọn ji ko lọ ninu wọn. O fi kun un pe iro ibọn ti awọn eeyan agbegbe naa gbọ ni wọn fi ranṣẹ pajawiri si awọn. Oju-ẹsẹ ni Dpo Kankara si ko awọn eeyan rẹ sodi, ti wọn si lọ sibẹ, ṣugbọn awọn ẹruuku naa ti lọ ki awọn agbofinro too debẹ, ti awọn si lọ sibẹ.

Gambo ni awọn agbebọn naa yinbọn mọ Pasitọ Haruna lapa, wọn si ji awọn obinrin marun-un ti wọn n mura lati lọ si ileejọsin lọjọ isinmi naa.

O fi kun un pe ileewosan ijọba to wa ni Kankara ni wọn sare gbe pasitọ ti wọn yinbọn fun naa lọ, bẹẹ ni awọn n sa gbogbo agbara lati gba awọn ti wọn ji gbe naa pada.

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Leave a Reply