Awọn agbebọn ji ọmọ Fulani gbe l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Awọn ikọ alaabo atawọn ọlọdẹ ti fọn sinu igbo to yi ilu Ora-Igbomina, nijọba ibilẹ Ifẹdayọ, nipinlẹ Ọṣun, ka lati ṣawari ọmọdebinrin kan tawọn agbebọn ji gbe nibẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde.

Nnkan bii aago meje alẹ la gbọ pe awọn agbebọn naa lọ si ile baba ọmọdebinrin naa, Alhaji Bayọ ninu Gaa Fulani ti wọn n gbe.

A gbọ pe lẹyin ti wọn yinbọn fun un, ṣugbọn ti ko wọle si i lara, ni wọn fibinu gbe ọkan lara awọn ọmọbinrin rẹ lọ sinu igbo.

Nigba ti wọn lọ tan ni baba yii atawọn araale rẹ figbe ta, latigba naa si ni awọn ọlọpaa, OPC, ọlọdẹ, figilante ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wa ninu igbo lati dọdẹ awọn agbebọn ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe awọn agbofinro ti wa ninu igbo lati gba ọmọbinrin ọhun silẹ lai fara pa.

Leave a Reply