Awọn agbebọn ji ọmọ oṣiṣẹ ọfiisi Buhari gbe ni Kaduna

Faith Adebọla

Niṣe ni iṣẹ ijinigbe awọn agbebọn tubọ n gogo si i nipinlẹ Kaduna lasiko yii, Sanusi Maikano, ọmọ oṣiṣẹ ọfiisi Aarẹ Mohammadu Buhari l’Abuja, Alaaji Abubakar Maikano, lawọn agbebọn naa ji gbe lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, wọn si ṣe bẹẹ wọ ọmọ naa wọgbo rau.

Ohun ta a gbọ ni pe niṣẹ lawọn janduku agbebọn bii mẹjọ kan tẹle ọmọ yii bo ṣe n dari rele lati oko baba rẹ to wa lagbegbe Gwantu, nijọba ibilẹ Sanga, nipinlẹ Kaduna. Wọn lasiko naa ti to bii aago mẹjọ aabọ alẹ.

Ojiji ni wọn lawọn agbebọn naa rẹbuu ọkọ ti ọmọ naa wa bo ṣe fẹẹ wọ ile rẹ. A gbọ pe wọn ko yinbọn rara, bẹẹ ni wọn o ṣe ẹnikẹni leṣe, wọọrọwọ ni wọn mu ọkunrin naa, ọkada ti wọn gbe wa ni wọn fi gbe e lọ.

Ọkan lara awọn iyawo rẹ sọ fawọn oniroyin pe “Bi ọkọ mi ṣe n wọle lawọn agbebọn naa wọle tẹle e, boya wọn ti n ṣọ ọ tẹlẹ ni, tabi wọn ti n tẹle e bọ lati oko to lọ, ọkan lara awọn agbebọn naa pariwo “Sanusi da, nibo lo wa?” a sọ fun wọn pe ko si nile, ṣugbọn wọn fesi pe awọn ri i bo ṣe bọọlẹ ninu mọto rẹ, to si wọle laipẹ yii.

Wọn kọkọ gan aburo Sanusi lapa, wọn lawọn maa pa a ti awọn ko ba ri Sanusi, nigba ti Sanusi si jade, wọn fi ọmọ naa silẹ, ni wọn ba mu ọkọ wa lọ, wọn o yinbọn rara, niṣe ni wọn rọra n sọrọ, wọn o fẹẹ pariwo.”

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn si lawọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati tọpasẹ awọn ajinigbe naa.

Leave a Reply