Awọn agbebọn ji ọmọ ọdun mejidinlogun gbe ni Magodo

Jọkẹ Amọri

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn mọlẹbi ọmọ ọdun mejidinlogun kan, Janet Fajinmi, tawọn ajinigbe gbe nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ṣi n wa a.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago marun-un aabọ ọjọ Satide, ọjọ kọkanla, oṣu kejila yii, ni awọn agbebọn kan deede ki ọmọbinrin naa mọlẹ Shangisha, CMD, to wa ni Magodo, niluu Eko, ti wọn si gbe e sa lọ.

Mọto Sienna alawọ dudu kan ti nọmba rẹ jẹ NNE-571-ZK, Anambra State, ni wọn fi ji ọmọ naa gbe.

Bi wọn si ti ji i gbe tan ni wọn jade si oju ọna marosẹ Eko si Ibadan, ko si ti i sẹni to mọ ibi ti wọn gbe ọmọbinrin naa lọ titi di ba a ṣe n sọ yii.

Wọn ti waa rọ ẹnikẹni to ba kofiri ọkọ naa ki wọn fi to awọn agbofinro leti.

Leave a Reply