Awọn agbebọn ji oyinbo meji gbe n’Ifẹwara

Florence Babaṣọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ijinigbe kan to ṣẹlẹ labule Okepa/Itikan, niluu Ifẹwara, lọjọ Aje oṣẹ yii.

Awọn oyinbo naa ni Messers Zhao Jian, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Wen to jẹ ọmọ aadọta ọdun.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla fi sita, ibudo iwakusa kan niluu naa lawọn janduku agbebọn naa ti ya bo awọn to n ṣiṣẹ nibẹ.

Meji lara awọn ẹṣọ alaabo ileeṣẹ aladaani kan ti wọn n ṣọ awọn oyinbo naa ni wọn kọkọ yinbọn lu ki wọn too ji awọn oyinbo gbe.

Ọpalọla ṣalaye pe wọn ti gbe awọn to fara pa naa lọ sileewosan, nigba ti awọn ikọ agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ gidigidi lati gba awọn oyinbo ti wọn ji lọ naa.

Leave a Reply