Awọn agbebọn ji pasitọ ijọ Deeper Life gbe ninu sọọsi rẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Pasitọ ijọ Deeper Life kan, Ọtamayọmi Ogedemgbe, lawọn ajinigbe kan tun ji gbe ninu ṣọọsi rẹ to wa niluu Irẹṣẹ, nitosi Akurẹ, lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Awọn agbebọn ọhun la gbọ pe wọn ya bo ṣọọsi ni nnkan bii aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹtalelogun alẹ ọjọ naa, ti wọn si fipa wọ Pasitọ Ogedemgbe sinu ọkọ Toyota Corolla dudu kan ti wọn gbe wa loju awọn ọmọ ijọ.

Ọkan ninu awọn ọmọ ijọ pasitọ náà tó bá awọn oniroyin sọrọ ni, o ku diẹ kí aago marun-un irọlẹ lu ni olusọaguntan naa ti de ni imurasilẹ fun eto isin ẹkọ Bibeli tí wọn maa n ṣe ni gbogbo ọjọ Aje, Mọnde, ọsọọṣẹ.

O ni ṣe lo da bii ẹni pe awọn ajinigbe ọhun ti n dọdẹ pasitọ awọn tẹlẹ nitori pe oun nikan ni wọn ji gbe laarin gbogbo awọn ti wọn wa ninu ṣọọsi lasiko ti eto ijọsin n lọ lọwọ.

Leave a Reply